Faith Adebọla
Eto iṣuna owo tijọba apapọ maa na lori iṣejọba lọdun 2021 ti kuro ni aba bayii, kinni naa ti dofin, o si ti di ilana tijọba maa fi ṣakoso lọdun to n bọ.
Oni, Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni Aarẹ Muhammadu Buhari buwọ lu abadofin tawọn aṣofin ile mejeeji panu-pọ le lori lọsẹ meji sẹyin, ti wọn si fi ẹda iwe naa ṣọwọ si ọfiisi Aarẹ fun ibuwọlu rẹ kiwee naa le bẹrẹ iṣẹ.
Apapọ owo ti iye rẹ jẹ tiriliọnu mẹtala, okoodinlẹgbẹta miliọnu o din mejila (#13,588,027,886,175) ni wọn fọwọ si lati na. Ninu owo yii, tiriliọnu mẹta ati miliọnu ọọdunrun ni wọn fẹẹ fi san lara gbese ti Naijiria jẹ awọn ilẹ okeere, tiriliọnu marun-un o le ẹgbẹta lo maa ba owo-oṣu, itọju awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn inawo abẹle lọ, nigba ti tiriliọnu mẹrin yoo lọ fun iṣẹ ilu ati ipese ohun amayedẹrun.
Lara awọn to pesẹ sibi ayẹyẹ to waye nileejọba naa ni Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, Olori awọn aṣofin agba, Ahmad Lawal, Abẹnugan ile aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, ati Akọwe fun ijọba apapọ, Boss Mustapha.