Boko Haram ti sọrọ, wọn ni ẹ ma laagun jinna, awọn ọmọleewe yin wa lọdọ wa

Aderounmu Kazeem

Bo ti ṣe n pe ọjọ karun-un lọ bayii ti wọn ti ji awọn ọmọ ileewe girama kan ko ni Kankara nipinlẹ Katsina, awọn janduku afẹmiṣofo Boko Haram ti  sọ pe awọn gan-an lawọn ṣiṣẹ ibi ọhun.

Ninu fidio ti ko ju iṣẹju mẹrin aabọ lọ ni agbẹnusọ wọn, Abubakar Shekau, ti sọ pe awọn lawọn ji awọn ọmọ ọhun gbe, ati pe ọmọleewe bii ọọdunrun (300) lo wa ni akata awọn bayii.

Koko ohun ti awọn janduku afẹmiṣofo yii sọ pe o mu awọn ṣiṣẹ ibi ọhun ko ju inu buruku to n bi awọn lọ nitori ti wọn n kọ awọn ọmọ naa lẹkọọ iwe mọ-ọn-kọ, mọ-ọn-ka, eyi ti ko ba ti Ọlọrun mu.

Alẹ ana, ọjọ Aje lawọn Boko Haram ti fi fidio ọhun sita, bẹẹ ni Shekau, sọ pe ko si ootọ kan ninu iroyin tawọn kan n gbe kiri wi pe awọn ti sọ ohun tawọn fẹ gan-an.

O fi kun un pe bi awọn ṣe kọlu ileewe Government Science Secondary School, ni Kankara, nipinlẹ Katsina, awọn fi ṣapọnle ẹsin Islam ni, ati pe eto ẹkọ mọ-ọn-kọ mọ-ọn-ka ti wọn n kọ wọn nileewe ọhun ko ba ilana Ọlọrun ati ti Anọbi mu rara.

Ninu ọrọ ẹ naa lo ti ni ki awọn eeyan ma wulẹ laagun jinna, awọn gan-an lawọn wa nidii ijinigbe ọhun, awọn ọmọ ti wọn n wa wa lọdọ awọn o.

 

Leave a Reply