Bọọsi jana mọ reluwee lẹnu n’Ilupeju, eeyan meji fara pa yannayanna

Faith Adebọla, Eko

Ẹka ti wọn ti n fawọn alaisan ni itọju pajawiri lọṣibitu jẹnẹra ni dẹrẹba to wa bọọsi Toyota Hiace kan ati ọkan ninu awọn ero inu ọkọ ọhun wa titi dasiko yii, nibi tawọn dokita ti n ṣapa lati doola ẹmi wọn latari bi wọn ṣe fara gbọgbẹ yannayanna nigba ti bọọsi naa jana mọ reluwee lẹnu l’Ekoo.
Agbegbe Ilupeju Bye-pass, ni Ilupeju, nitosi Muṣin, nijamba ọhun ti waye laaarọ Ọjọọru, ọsẹ yii.
Ba a ṣe gbọ, wọn ni niṣe ni dẹrẹba bọọsi ti nọmba rẹ jẹ EKY 888 XW ṣafojudi si reluwee to n bọ ọhun, tori awọn ẹṣọ alaabo ti da awọn ọkọ duro lọtun-un losi ki reluwee naa le kọja, ọkunrin yii si wa lara awọn ti wọn ti da duro, bo tilẹ jẹ pe iwaju lo wa.
Lojiji ni wọn ni awakọ yii bẹ lau pẹlu ọkọ rẹ, boya o ronu pe oun aa ti sọda tan ki reluwee too de, ṣugbọn ọkọ naa pana mọ ọn lọwọ, bo ṣe n ṣina ọkọ lati sare kọja ni reluwee ka a mọ, o si kọ lu ọkọ rẹ.
Iku ti i ba pa ni, bo ba ṣi ni ni fila, ka dupẹ ni, lọrọ dẹrẹba naa da, reluwee gba bọọsi rẹ lẹgbẹẹ, oun ati ẹni kan ṣeṣe, ṣugbọn ko sẹni to ku.
Ọpẹlọpẹ awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si lilọ bibọ ọkọ l’Ekoo, LASTMA, atawọn ẹṣọ alaabo Neighbourhood, awọn ni wọn kọkọ ṣaajo wọn, wọn fun wọn ni itọju iṣegun oju-ẹsẹ, lẹyin eyi ni wọn gbe wọn lọ sọsibitu to wa n’Ikẹja.
Bakan naa lawọn ẹṣọ LASTMA gbe irinṣẹ wọn wa, ti wọn wọ bọọsi naa lọ si teṣan ọlọpaa reluwee, to wa ni Mushin, ko ma baa ṣediwọ fun igbokegbodo ọkọ.

Leave a Reply