Bọọsi tawọn akẹkọọ wa ninu rẹ gbina lojiji l’Akungba Akoko, awọn mẹẹẹdogun fara pa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn akẹkọọ bii mẹẹẹdogun ni wọn fara pa yannayanna lasiko ti bọọsi ti wọn wa ninu rẹ deedee gbina lojiji lori ere niluu Akungba Akoko laaarọ pọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan to pe ara rẹ ni Olumide pe iṣẹlẹ yii waye lasiko ti awakọ bọọsi naa n kaakiri gẹgẹ bii iṣe rẹ lati ko awọn akẹkọọ kan lọ sile-iwe.
O ni ṣe lawọn deedee ri eefin ina to n jade lati inu ọkọ wọn nibi tawọn jokoo si, leyii to mu ki oun atawọn eeyan kan ti awọn jọ n ṣere sare lọ sibẹ lati doola ẹmi awọn to wa ninu ọkọ naa.
O ni gbogbo gilaasi ẹyin ọkọ naa lawọn fọ ki awọn too ri awọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ ọhun ko jade lẹyin ti gbogbo akitiyan awọn lati silẹkun ọkọ ọhun ja si pabo.
Ọpọlọpọ awọn obi ti wọn lọmọ si ileewe aladaani naa la gbọ pe idaamu de ba ni kete ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ ijamba ina ọhun, gbogbo wọn ni wọn si sare mori le ibẹ lati doola ẹmi ọmọ wọn.
Ileewosan ijọba to wa ni Iwarọ Ọka Akoko, ni wọn kọkọ ko awọn ọmọ to fara pa ninu iṣẹlẹ naa lọ fun itọju, ki wọn too tun pada ko wọn lọ si ọsibitu ijọba apapọ to wa niluu Ọwọ, nibi ti wọn wa lasiko ta a n ko iroyin yii jọ.

Leave a Reply