Boya ni Dare ati Felix yoo bọ ninu okun adajọ o, awọn ọmọ keekeeke ni wọn fipa ba lo pọ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn gende meji kan, Oluwadare Tọlaju ati Felix Wonux, ti n jẹjọ lori ẹsun fifipa ba awọn ọmọ keekeekee lo pọ l’Akurẹ.

Awọn mejeeji ti wọn fara han ni kootu Majisreeti ọtọọtọ l’Akurẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ladajọ ni ki wọn ṣi lọọ fi wọn pamọ si ọgba ẹwọn titi tile-ẹjọ to n gbọ ẹsun wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Ẹsun ti wọn fi kan Tọlaju, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ni pe ọmọdebinrin kan ti ko ti i ju bii ọmọ ọdun mẹfa pere lọ ni wọn lo ki mọlẹ, to si fipa ṣe kinni fun un lọjọ kẹta, oṣu kẹjọ, ọdun yii lagbegbe Kajọla, Ala, nitosi Akurẹ.

Agbefọba, Oniyere Taiwo, ni afurasi afipabanilopọ naa ti ṣẹ si abala ofin okoolelugba din meji (218) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006 nitori pe kede layẹwo awọn dokita fidi rẹ mulẹ pe loootọ lo fipa ṣe ere gele pẹlu ọmọ kekere naa.

Oniyere ni ki ile-ẹjọ paṣẹ ki wọn si fi olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn titi ti imọran yoo fi wa lati ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran.

Gbogbo ẹbẹ ati aba yii ni Onidaajọ I. O. Abu fọwọ si nigba to n gbe ìpinnu rẹ kalẹ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ladajọ ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju lori ọrọ Tọlaju.

Ẹni ọdun mọkanlelogun ni afurasi Felix to jẹ afurasi ọdaran keji, ọmọdebinrin ẹni ọdun mọkanla ni wọn loun fipa ba lo pọ lọjọ kẹjọ, oṣu yii.

Iṣẹlẹ ọhun la gbọ pe o waye laduugbo kan ti wọn n pe ni Ọlọrungbohunmi, Ilẹ-Oluji, nijọba ibilẹ Ilẹ-Oluji /Oke-Igbo.

Ọlọpaa to n ṣoju ijọba, Ripẹtọ Augustine Omhenimhen, ni ẹsun to lagbara ni wọn fi kan olujẹjọ ọhun eyi ti wọn ki i gba beeli rẹ.

Ẹbẹ ti oun naa fi siwaju adajọ ni pe ko paṣẹ fifi ọkunrin naa pamọ sọgba ẹwọn titi ti esi imọran ti wọn n reti lati ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran yoo fi tẹ awọn lọwọ.

Onidaajọ Yakubu to n gbọ ẹjọ naa fi aidunnu rẹ han si bi iwa ifipabanilopọ ṣe n pọ sii lawujọ pẹlu gbogbo akitiyan ti ijọba ati ileesẹ eto idajọ n sa.

Ẹnikẹni to ba ti jẹbi ẹsun yii lo ni o gbọdọ jiya to tọ labẹ ofin, ko le jẹ ẹkọ nla fawọn to ba kundun iru iwakiwa yii.

Lẹyin eyi loun naa pasẹ pe ki Felix ṣi lọọ maa gbatẹgun ninu ọgba ẹwọn titi di ọjọ kọkandinlọgbọn, osu kẹsan-an, ọdun ta a wa yii, ti igbẹjọ rẹ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply