Brazil sọ ede Yoruba di dandan fawọn ileewe alakọọbẹrẹ ati girama

Adefunkẹ Adebiyi

Ni bayii, ede Yoruba ti di ajọlo ti ijọba orilẹ-ede Brazil fọwọ si, ti wọn si ti fontẹ lu u bi ede to jẹ dandan fawọn akẹkọọ lati kọ nileewe alakọọbẹrẹ ati ti girama wọn.

Dokita Sérgio Sá leitão, iyẹn minisita fun aṣa lorilẹ-ede Brazil lo sọ eyi di mimọ lopin ọsẹ to kọja. O ni ijọba Brazil ti fi dandan le e pe awọn akẹkọọ gbọdọ maa kọ ẹkọ nipa ilẹ Adulawọ, wọn si ti fi ede Yoruba kun ede ajumọsọ wọn.

Nibi eto kan ti ileewe nipa ede ilẹ Afrika ṣe ni Yunifasiti Sao Paulo, ni Brazil lo ti sọrọ yii. Awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria pataki kunbi eto naa, awọn onpitan, awọn ọmọwe rẹpẹtẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gẹgẹ bi minisita ilẹ Brazil naa ṣe wi, o ni bi wọn ṣe mu ede Yoruba wọnu ẹkọ nilẹ awọn yii yoo jẹ kawọn ọmọ Brazil ti wọn jẹ adulawọ mọ pupọ si i nipa orirun wọn. Yoo si tun jẹ ki awọn ede mi-in ti wọn n sọ nibẹ ye wọn daadaa yatọ si ede Potogi ti i ṣe ajọlo ti wọn n lọ.

Sérgio Sá leitão ko ṣai mẹnuba ipa ti Brazil ko ninu ọdun aṣa ati iṣe ti Naijiria ṣe niluu Eko lọdun 1977, iyẹn FESTAC 77.

O ni awọn eto bii ipatẹ nnkan aṣa to maa n waye lọdọọdun ni Naijiria tubọ n ṣafihan awọn nnkan ti a ni, pẹlu awọn agba Yoruba ti wọn jẹ ọnkọwe, awọn bii Yinka Shọnibarẹ, Adeyinka Ọlaiya, El Anatsu ati Ọjọgbọn agba, Wande Abimbọla.

Bakan naa ni Ọjọgbọn Mário Vargas Llosa sọ ọ di mimọ pe iran Yoruba pẹlu aṣa wọn ti ran agbaye lọwọ. O ni baye ṣe bẹrẹ ni Ifa ti wa, o ṣi wa doni, o si yẹ kawọn eeyan da a mọ ju bo ṣe wa tẹlẹ lọ. O ni ede Yoruba ti kuro lede ti eeyan yoo maa foju ẹya kan ṣoṣo wo, o ti di ede agbaye.

Ọmọ Naijiria kan, Adeyinka Ọlaiya, to jẹ ayaworan, naa sọrọ nibi eto yii. O ṣalaye anfaani ti sisọ ede Yoruba yoo mu ba orilẹ-ede Brazil, bi wọn ba fi tọwọ-tẹsẹ gba a sinu ẹkọ ti wọn n kọ nileewe wọn.

Gẹgẹ bi Ọlaiya ṣe wi, beeyan ba n gbe nibi kan ti wọn n pe ni Salvador, ni Brazil, bii igba teeyan n gbe lawọn ilẹ Yoruba ni Naijiria ni, nitori awọn ọmọ Yoruba lo pọ ni Salvador.

‘Ọpọlọpọ aṣa ati iṣe to foju han ju ni Brazil yii lo jẹ pe awọn ẹbi lati ilẹ Yoruba ni wọn ko o wa, nitori ẹ lawọn ọrọ bii Akara, Dende, Iyalode, Babalawo, Iyalawo ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn jẹ ọrọ Yoruba ṣe wa ninu ede wọn titi doni.’ Bẹẹ ni Ọlaiya wi.

Leave a Reply