Buhari ati iyawo ẹ lọ si Equitorial Guinea

Faith Adebọla

Lai ka bi oriṣiiriṣii apero abẹnu ati eto idibo lati yan awọn ti yoo dije fun oniruuruu ipo lasiko idibo gbogbogboo ọdun 2023 lorukọ ẹgbẹ oṣelu rẹ, All Progressives Congress, (APC), eyi to n lọ lọwọ si, ati bi eto idibo lati yan oludije funpo aarẹ laarin awọn mẹtalelogun to fẹẹ dije lọsẹ to n bọ, Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari ati iyawo rẹ, Aisha, ti tẹkọ leti lọ sorileede Equitorial Guinea, lati lọọ ṣepade ọlọjọ-mẹta kan.
Oludamọran pataki si Aarẹ lori eto iroyin, Mallam Garba Shehu, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee yii.
Shehu ni apero akanṣe kan, eyi ti gbogbo awọn alaṣẹ orileede ilẹ Afrika yoo pesẹ si ninu ẹgbẹ wọn, African Union (AU), yoo waye lorileede naa, bẹrẹ lati ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un taa wa yii, si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu naa. Ọrọ nipa eto aabo lo ni wọn fẹẹ fikun lukun le lori lọhun-un.
O lawọn olori naa tun maa jiroro nipa iwa abeṣe awọn afẹmiṣofo to gbode, ati bawọn ologun ṣe n fibọn gbajọba lawọn orileede adulawọ kan. Bẹẹ ni wọn maa yiiri akoba ti awọn nnkan wọnyi n ṣe fun eto iwọle-wọde orileede kan si omi-in ati awọn ogunlende gbogbo wo.
O ni ipade naa maa fun Buhari lanfaani lati fọrọ werọ pẹlu awọn aṣaaju orileede ẹlẹgbẹ rẹ.
Lara awọn ti wọn ba Aarẹ kọwọọrin ni, iyawo rẹ, Abilekọ Aisha Buhari, Minisita ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama, Minisita feto aabo, Ajagun-fẹyinti Bashir Salihi Magashi, Minisita lori eto eto to jẹ mọ aanu ati kiko ni yọ lọwọ ajalu, Sadiya Umar Farouq. Oludamọran apapọ lori eto aabo, Babagana Monguno, ati Alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria lẹyin odi, Abilekọ Abikẹ Dabiri-Erewa, pẹlu awọn mi-in.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Buhari ṣabẹwo si orileede United Arab Emirate, niluu Dubai, lati lọọ bawọn kẹdun aarẹ wọn to doloogbe, o si ki aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo tẹle e.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: