Buhari balẹ si Maiduguri, o fẹẹ ṣile ti wọn kọ fawọn ogunlende

Faith Adebọla

 Nnkan bii aago mẹwaa owurọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni baaluu awọn ọmọ ogun ofurufu kan to gbe Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, balẹ si ibudo awọn ologun niluu Maiduguri, nipinlẹ Borno, latari abẹwo ọlọjọ kan ti Aarẹ naa n ṣe sipinlẹ ọhun.

Wamuwamu ni awọn ẹṣọ ologun atawọn ọlọpaa duro lati pese aabo to peye fun Aarẹ, bẹẹ ni gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum, wa nikalẹ lati ki i kaabọ.

Lasiko abẹwo ọhun, ireti wa pe Buhari yoo ṣi ile oniyara ẹgbẹrun kan tijọba apapọ ati tipinlẹ naa pawọ-pọ kọ fawọn ti wahala Boko Haram ti sọ di alainilelori, iyẹn awọn ogunlende, (Internally Displaced Persons) yoo si sọrọ itunu fun wọn.

Bakan naa ni Buhari yoo ba awọn ọmoogun ikọ Operation Hadin Kai sọrọ, awọn ni wọn n koju ija ati akọlu ẹgbẹ afẹmiṣofo Boko Haram lagbegbe naa.

Aarẹ Buhari yoo tun ṣabẹwo si aafin ọba Shehu tilẹ Borno, yoo si fikunlukun pẹlu awọn olori ologun ilẹ wa lati wa ojutuu si iṣoro awọn janduku, eeṣin-o-kọ’ku ti wọn n daamu awọn eeyan ipinlẹ naa.

Lara awọn to tẹle Aarẹ Buhari lẹnu abẹwo rẹ ni olori awọn ologun apapọ, Jẹnẹra Lucky Irabor, ati olori awọn ọmoogun ori omi, ti oju ofurufu ati awọn ṣọja.

Leave a Reply