Buhari bawọn ọmọ Naijiria sọrọ, o ni, ‘Awọn kan ro pe ọlẹ ati oku ojo lasan ni wa’

Olori ijọba ilẹ wa, Ọgagun Muhammed Buhari ti sọ pe ohun to jẹ ki awọn woran fungba diẹ lori ọrọ wahala ti iwọde SARS da silẹ ni pe awọn eeyan kan ro pe ojo ati ọlẹ lawọn ti awon n ṣejoba ni. O ni, “Nigba ti ọro yii kọkọ bẹrẹ, ti awọn ọdọ wa ni awọn ko fẹ SARS mọ, ohun ti a ṣe ni lati fagi le ikọ naa, ti a si gbe awọn eto tuntun mi-in dide. Ṣugbọn awọn kan ro pe ojo ni wa, tabi pe a ko lagbara, awon si le halẹ mo wa, ni won ba tun bẹrẹ si i beere nnkan mi-in lọwọ!”

Nigba ti Aarẹ Muhammadu Buhari n ba gbogbo ilu sọrọ nirọlẹ oni yii lo sọ bẹẹ, pẹlu alaye pe awọn ohun to pada waa ṣẹlẹ ko tẹ oun lọrun, nitori ọrọ naa la iku lọ, ẹmi ṣofo, dukia bajẹ, ohun to si ṣẹlẹ si Ọba ilu Eko ko ṣee maa fẹnu sọ. Buhari ni gbogbo eleyii lo dun oun, ṣugbọn ijọba ko le laju silẹ ki awọn kan maa halẹ mọ ọn, tabi ki wọn maa ba dukia ati nnkan-ini awọn eeyan ati ti ijọba jẹ.

O ni oun rọ awọn ọdọ ki wọn ma jẹ ki ẹnikẹni ti wọn mọ, ki wọn mura lati lo awọn ohun ti awọn ti ṣeto silẹ fun wọn, ki wọn ma si ṣe iwọde ti ko nidii, nitori ọpọ ohun ti wọn n beere fun lawọn ti ṣe. Buhari ni ijọba yii yoo daabo bo wọn, wọn yoo si maa pese fun wọn, ṣugbọn awọn ko ni i jẹ ki wọn di awọn araalu to ku lọwọ, tabi ki wọn ba nnkan wọn jẹ o.

One thought on “Buhari bawọn ọmọ Naijiria sọrọ, o ni, ‘Awọn kan ro pe ọlẹ ati oku ojo lasan ni wa’

Leave a Reply