Faith Adebọla
Aarẹ orileede wa, Muhammadu Buhari, ti rawọ ẹbẹ sawọn gomina ẹgbẹ oṣelu rẹ, All Progressives Congress (APC), ati alaga ẹgbẹ naa, Abdullahi Adamu, pe ki wọn foun lanfaani lati yan ẹni to maa gbapo aarẹ lọwọ oun nigba toun ba fẹẹ gbejọba silẹ lọdun 2023, o ni kaluku wọn lo maa n yan ẹni to maa gbapo ẹ lawọn ipinlẹ wọn, kari aye si lawọn aarẹ maa n yan ẹni ti wọn fẹ ko jẹ aarẹ lẹyin wọn ninu ẹgbẹ oṣelu wọn, tori ẹ, oun fẹ ki wọn gbaruku ti ẹnikẹni toun ba fa kalẹ lati jẹ oludije fun ipo aarẹ lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ APC to maa waye jọ Aje, Mọnde, to n bọ yii.
Buhari sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un yii, lasiko to ṣepade pataki kan pẹlu awọn gomina ọhun. Wamuwamu lẹsẹ awọn gomina mejilelogun to wa lẹgbẹ APC pe sipade naa, ni gbọngan apero to wa nileeṣẹ aarẹ, l’Abuja.
Buhari ni kawọn gomina naa lọọ ronu lori ẹni to ni awọn animọ ati amuyẹ to yẹ aarẹ, ki tọhun si jẹ ẹni to le mu ki ẹgbẹ APC jawe olubori lasiko idibo gbogbogboo to n bọ lọdun to n bọ.
Ninu atẹjade kan ti Fẹmi Adeṣina, oludamọran pataki si aarẹ lori eto iroyin ati ikede, fi lede, o ni Buhari sọ fawọn gomina naa pe:
“Bi mo ṣe bẹrẹ ọdun to kẹyin ninu saa keji iṣakoso mi gẹgẹ bii aarẹ orileede Naijiria yii, ati gẹgẹ bii olori ẹgbẹ oṣelu yii, mo ri i pe o pọn dandan fun mi lati pese idari, ki n si tukọ ẹgbẹ yii la asiko ta a fẹ yan olori tuntun yii kọja si igba ta a maa fa iṣakoso orileede yii le e lọwọ. Idari yii ṣe pataki ki ẹgbẹ oṣelu wa le wa niṣọkan, ko si lagbara daadaa.
“Afojusun wa gbọdọ jẹ bi ẹgbẹ oṣelu wa ṣe maa jawe olubori, ẹni ta a fẹ fa kalẹ gbọdọ jẹ ẹni tawọn ọmọ Naijiria le fọwọ sọya le lori pe alaṣeyege to ṣee fọkan tẹ ni.”
Adeṣina ni aarẹ tun ran awọn gomina naa leti pe awọn gbọdọ ṣiṣẹ lori didin awọn oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ naa ku ko too di ọjọ idibo abẹlẹ ẹgbẹ, tori omi to ba mọ niwọn leeyan n rẹ ila si. Buhari ni ifikun lukun ati ajọsọ ọrọ gbọdọ waye lati ri i pe awọn nnkan toun sọ wọnyi wa si imuṣẹ.
O ni Alaga apapọ ti fọkan aarẹ balẹ pe gbogbo isapa lawọn maa ṣe lati ri i pe awọn oludije naa ko ju mẹrin lọ, ko too di ọjọ idibo abẹle naa.