Buhari fariga, ko yọju sawọn aṣofin ti wọn ranṣẹ pe e

 Jide Alabi

Gẹgẹ iwoye awọn eeyan tẹlẹ pe o ṣee ṣe ki Aarẹ Muhammadu Buhari ma yọju si awọn aṣọfin l’Ọjọbọ, Tọsidee, nibi ti wọn ti pe e ko waa ṣalaye akitiyan ijọba ẹ lori bi ọrọ eto aabo ṣe da bayii ni Naijiria.

Lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun yii, gan-an lawọn ọmọ ile-igbimọ aṣoju-ṣofin sọ ọ laarin ara wọn pe o ṣe pataki ki Buhari waa sọ tẹnu ẹ, ti Aarẹ naa si gba lati yọju si wọn loni-in Ọjọbọ, ọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun yii.

Nipinlẹ Borno lọhun-un lawọn janduku afẹmi-ṣofo kan ti kọ lu awọn agbẹ onirẹsi ti wọn le logoji, ti wọn  si pa wọn nipakupa laipẹ yii. Iṣelẹ yii gan an ni wọn lo mu awọn aṣofin sọ pe nibi ti wahala iṣekupani de lorilẹ-ede yii loni-in, o ti di dandan ki awon eeyan Naijira gbọ lẹnu Buhari, ohun ti ijọba rẹ n ṣe nipa eto aabo.

Ṣa o, Minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami, ti kọkọ sọ lọjọ Wẹsidee pe awọn aṣofin ko lẹtọọ lati fipa mu Aarẹ lati waa sọ tẹnu ẹ nipa ọrọ aabo.

Yatọ si eyi, ALAROYE tun gbọ pe ohun to mu Aarẹ Buhari ma yọju ni bi awọn eeyan kan ṣe ta a lolobo pe awọn aṣofin kan ti n duro de e lati fi awọn ibeere kan to lagbara yẹyẹ ẹ, iyẹn to ba yọju si wọn loni-in.

Leave a Reply