Buhari fẹẹ lọọ ri awọn dokita rẹ ni London

Adewumi Adegoke

Olori orileede wa, Aarẹ  Ọgagun Muhammadu Buhari, ti fi orileede Naijiria silẹ lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. Ilu London ni Aarẹ n lọ, nibi ti yoo ti ri awọn dokita rẹ fun ayẹwo ara rẹ, bẹẹ ni yoo si tun lo ọjọ mẹrin ni Nairobi, lorilede Kenya, nibi ti yoo ti kopa nibi ajọdun aadọta ọdun ayẹyẹ ajọ agbaye kan ti wọn n pe ni United Nations Enviromental Programme ti yoo waye lọjọ kẹta si ikẹrin oṣu Kẹta yii.

Atẹjade Ti Oludamọran Pataki Aarẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, fi sita laaarọ ọjọ Iṣẹgun sọ pe Buhari n lọ si ilu London fun ayẹwo ara rẹ, yoo si gba a to ọsẹ meji gbako ko too pada wa.

Adeṣina ni, ‘‘Ni ibamu pẹlu iwe ipe ti ojugba rẹ lati orileee Kenya, Uruh Kenyatta, Aarẹ Buhari yoo fi orileede Naijiria silẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, lati kopa ninu ayẹyẹ aadọta ọdun  United Nations Enviromental Programme, ti yoo waye laarin ọjọ kẹta si ikẹrin ni Nairobi, Kenya.

‘‘Lati Kenya ni Aarẹ yoo ti tatapo si London, nibi ti yoo ti lọọ ri awọn dokita rẹ lati ṣayẹwo ilera rẹ.’’

Leave a Reply