Buhari fọwọ si atunṣe owo-oṣu ati ọdun tawọn tiṣa yoo maa lo lẹnu iṣe 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ awọn tiṣa lagbaaye ni Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari, fọwọ si atunṣe owo-oṣu tawọn tiṣa n gba, bẹẹ lo ni ki wọn ṣatunṣe si ọdun marundinlogoji (35) to jẹ gbedeke ti wọn n lo lẹnu iṣẹ ọba, ki wọn sọ ọ di ogoji ọdun.

Minisita fun eto ẹkọ lorilẹ-ede yii, Adamu Adamu, to ṣoju Buhari l’Abuja lo sọ eyi di mimọ, alaye to si wa nibẹ ni pe iyatọ yoo de ba owo-oṣu tawọn olukọ ijọba n gba, bẹẹ si ni agbeyẹwo yoo waye lori ọdun marundinlogoji to jẹ asiko ifẹyinti, wọn yoo gbe e si ogoji ọdun bi ayẹwo naa ba so didun.

Aarẹ gbe igbesẹ yii lati ṣe koriya fawọn tiṣa, bẹẹ lo si tun jẹ ipenija fun wọn lati tun jara mọṣẹ si i.

Leave a Reply