Buhari gbalejo awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe ni Katsina

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni Aarẹ Muhammadu Buhari gbalejo awọn akẹkọọ ileewe ijọba to wa ni Kankara, nipinlẹ Katsina, ti awọn ajinigbe ya bo, ti wọn si ko awọn bii ọọdunrun le diẹ ninu awọn akẹkọọ naa lọ.

Lasiko ti Aarẹ n ba awọn akẹkọọ naa sọrọ ni Banquet Hall, to wa nile ijọba, nipinlẹ Katsina, lo gba awọn ọmọ naa niyanju pe ki awọn akẹkọọ yii ma jẹ ki iṣẹlẹ to ṣẹlẹ naa, ati iriri ti wọn ni lọwọ awọn janduku ọhun da omi tutu si wọn lọkan, ki wọn kọju mọ iwe wọn daadaa.

Buhari to ṣalaye awọn ohun ti oun naa dojukọ laye sọ pe oun ko jẹ ki awọn idojukọ yii di oun lọọ lati tẹsiwaju.

Aarẹ ni, ‘‘Mo ki ẹyin akẹkọọ yii ku oriire, ẹ ma jẹ ki iriri yin lọdọ awọn janduku yii da omi tutu si yin lọkan, ẹ gbagbe gbogbo ohun to ti ṣẹlẹ, kẹ ẹ si kọju mọ iwe yin.

‘‘Ijọba yoo tẹsiwaju lati pese eto aabo to yẹ kaakiri awọn ileewe lorileede yii.’’

O waa rọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo lati maa fi ootọ inu ati ibẹru Ọlọrun ṣiṣẹ wọn, bẹẹ lo dupẹ lọwọ Gomina Aminu Masari fun akitiyan rẹ lati ri i pe wọn tu awọn ọmọ naa silẹ.

Leave a Reply