Buhari juko ọrọ lu Ọbasanjọ, o letekete rẹ ni ko jẹ ki Bisi Akande ṣe gomina lẹẹkeji

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Nibi ayẹyẹ kan ti wọn ṣe fun gomina ipinlẹ Ọṣun nigba kan, Oloye Bisi Akande, ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti ju oko ọrọ ranṣẹ si aarẹ tẹlẹ lorilẹ-ede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ. Buhari sọ pe Ọbasanjọ lo gbegi dina fun Bisi Akande tiyẹn ko fi ri gomina ṣe lẹẹkeji mọ, o ni Ọbasanjọ lo yiwọ pada fun un pẹlu etekete.

 Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹwaa yii, ni ayẹyẹ ọhun waye niluu Eko, nibi ti wọn ti ṣefilọlẹ iwe ti Oloye Bisi Akande kọ nipa aye rẹ, eyi to pe ni ‘My Participations.’

Awọn eeyan nla nla lo pejọ si gbọngan ayẹyẹ ti Buhari ti sọrọ yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu pẹlu Gomina Babajide Sanwo-Olu naa ko gbẹyin.

Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe, “Gbogbo wa la mọ pe Akande atawọn gomina AD kan lo fori ko etekete ti Ọbasanjọ da silẹ nigba naa, ti ko jẹ ko le ṣe gomina mọ. Aṣiwaju Tinubu nikan to ta ku lo yọ lọwọ Ọbasanjọ.

“ Loootọ lohun to ṣẹlẹ naa dun un, ṣugbọn nitori pe Musulumi ododo ni, o gba pe ara awọn ifasẹyin ile aye ni, o si n wo ọjọ iwaju lati le sin orilẹ-ede yii si i” Bẹẹ ni Buhari wi nipa Oloye Bisi Akande ati Ọbasanjọ.

Aarẹ fi kun un pe oloṣelu pataki ti ki i gba riba ni Bisi Akande, o ni atoofiṣẹ-ogun-ran ọkunrin ni.

Bi Buhari ṣe sọrọ yii lawọn eeyan ti n reti esi latọdọ Ọbasanjọ, wọn ni baba naa yoo wa esi to le fun Buhari to ba ya, bi ko si ṣe tii dahun yii, boya ọjọ ọrọ ko ti i to ni.

 

Leave a Reply