Buhari kẹdun iku awọn ọmọleewe rẹpẹte tọkọ akẹru pa l’Ojodu

Faith Adebọla, Eko

Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, ti kẹdun iku ojiji to pa awọn akẹkọọ rẹpẹtẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu kejila, ọdun yii, lọna Iṣhẹri, lagbegbe Ojodu, nipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ fun Aarẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, sọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ninu atẹjade to fi lede lorukọ Aarẹ pe ijọba yoo ṣiṣẹ lori ọna ti iru iṣẹlẹ aburu bii eyi ko fi ni i maa waye.

Atẹjade naa ka lapa kan pe:

“Aarẹ Muhammadu Buhari ṣedaro pẹlu obi, awọn mọlẹbi, ara, ọrẹ ati ojulumọ awọn ọmọleewe Ojodu Grammar School, ti wọn padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye lọjọ Tusidee, lọna Iṣẹri, Ojodu, l’Ekoo.

Bakan naa ni Aarẹ Buhari ba ijọba ipinlẹ Eko, awọn eeyan ilu Eko ati awọn alaṣẹ ileewe tọrọ yii kan kẹdun gidigidi lori ajalu to n mara roni yii, nibi ti iku ojiji ti n da ẹmi awọn ogo wẹẹrẹ ati ireti ọjọ-ọla wa, legbodo.

Aarẹ Buhari ṣadura pe ki Ọlọrun Olodumare tu awọn obi to n ṣọfọ wọnyi ninu, ko si bu ororo itura sọkan awọn mọlẹbi ati ọrẹ wọn, ki wọn le mọkan le ni’ru asiko ti ibanujẹ n sori agba kodo yii.”

Leave a Reply