Buhari ki Joe Biden ku oriire, o ni o kaabọ sawujọ awọn aarẹ agbaye

Aarẹ Muhammadu Buhari ti pẹlu awọn olori orilẹ-ede agbaye yooku ki Ọgbẹni Joe Biden, ku oriire

Lori ikanni abẹyẹfo rẹ ni Ọgbẹni Garba Shehu, to jẹ Oludamọran pataki lori eto iroyin kọ ọ si lorukọ Buhari, lo ti ki í kú oríire.
O ni, “Mo ki Aarẹ tuntun tí wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni ilẹ Amẹrika Joe Biden, ku oriire, paapaa lasiko ti gbogbo agbaye wa ninu ibẹru-bojo. Eto idibo to gbe e wọle yii tubọ fidi ẹ mulẹ pe ohun to dara ni eto ijọba dẹmokiresi.
Ṣiwaju sí í, o ni irufẹ eto ijọba ọhun gan-an lo maa n fun awọn eeyan lanfaani lati dibo yan olori tuntun lọna alaafia ati irọrun.

 

Leave a Reply