Buhari kilọ fun wọn lAmẹrika, o ni, ‘Ẹ ma da sọrọ ti o kan yin o’

Aderounmu Kazeem

Ninu ọrọ ti Aarẹ Muhammed Buhari, sọ laṣalẹ ana lo ti kilọ fawọn ilẹ okeere ki wọn ṣọra wọn daadaa, ki wọn yee da si ohun ti ko kan wọn nipa Naijiria.

Bi ọrọ ọhun ti ṣe ba awọn orilẹ-ede to sunmọ wa wi, bẹẹ ni Buhari, sọ pe awọn to wa lajọ agbaye paapaa gbọdọ ṣọra wọn daadaa ki wọn too maa da sọrọ ti wọn ko ba mọdi ẹ.

Ṣẹ, ko si orilẹ-ede to gbọ ohun tawọn ṣoja ṣe fawọn to n ṣe iwọde ni too-geeti Lẹki, ti wọn ko bu ẹnu atẹ lu ohun ti ijọba Naijiria ṣe, paapaa bi Aarẹ Muhammed Buhari, ṣe kọ ti ko sọ ohunkohun pẹlu bi wahala ọhun ṣe pọ tọ lọjọ Iṣẹgun titi wọ Ọjoru, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Bo si tilẹ jẹ pe Buhari ko darukọ orilẹ-ede kan pato, oko ọrọ naa jọ ti Amẹrika pupọ, nitori orilẹ-ede naa lo kọkọ jade lati sọ pe inu awọn ko dun si Buhari ati ijọba rẹ, nitori ohun ti wọn ṣe, ijọba wa ko si fesi titi ti Aarẹ fi bọ si ori afẹfẹ.

Ni kete ti Buhari si bọ sori afẹfẹ naa lo ti fun kaluku wọn lesi wọn pẹlu ikilọ to lagbara. Ohun to si sọ ni pe wọn ko lẹtọọ lati kọ oun bi oun yoo ṣe dari akoso ijọba Naijiria.

O ni, “Fun ẹyin orilẹ-ede tẹ ẹ sunmọ wa, atawọn ti wọn wa ni ajọ agbaye, a dupẹ lọwọ yin fun ifẹ tẹ ẹ ti fi han lori rogbodiyan to n ṣẹlẹ ni Naijiria, ṣụgbọn yoo wu mi ki ẹ maa ṣewadii daadaa lati mọ bi ọrọ ṣe jẹ gan-an ki ẹ too maa da sọrọ orilẹ-ede ti ki i ṣe tiyin.

“Ohun to buru ni, ti ẹ ko ba mọ bi ọrọ ṣe jẹ, ti ẹ kan ṣadeede ja lu u. Yoo dara ti ẹ ba le sọra yin daadaa, ki ẹ ma ṣe da sọrọ ti o kan yin rara.”

Bi Buhari, ti ṣe sọrọ yii lana-an niyẹn, bẹẹ lo jẹ pe pupọ ninu awọn ọmọ Naijiria ni wọn sọ pe fun bii iṣeju mejila to fi ba awọn sọrọ, bii ẹni fi akoko awọn ṣofo danu lasan ni, nitori ko fẹẹ ma si ọrọ gidi kan lẹnu Aarẹ Buhari.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lanlọọdu ati getimaanu pa ọmọọdun mẹrin, wọn yọ ẹya ara ẹ lati fi ṣoogun owo

Faith Adebọla Diẹ lo ku kawọn araalu tinu n bi dana sun baba getimaanu kan …

3 comments

  1. Aye baba yii tinlbaje o

  2. Jimoh-fasola Olamilekan John

    Kò ye kí ògbéni Buhari so béè rárá,òrò náà kò mú opolo dání.

  3. Orire loburu were tikoni opolo won tunpe si akiyesi kotun ronun

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: