Agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Fẹmi Adeṣina, sọ lana-an ode yii pe ohun ti ọpọ eeyan ko mọ nipa ọga oun ni wọn n sọ, ati pe awọn ti wọn n sọ pe olori ijọba Naijiria naa lahun ko mọ ọn dele rara.
Nigba to n ki Buhari kuu oriire ayẹyẹ ọjọọbi ọdun mejidinlọgọrin (78) rẹ lo sọrọ naa, to ni ẹni to ba n fi oju ahun wo Buhari, tọhun ko mọ ohun to n ṣe e rara. Adeṣina ni awọn ọjọ kan wa ti Buhari ṣe oun ni awọn oore kan ti oun ko ro, ti oun ko si le gbagbe, eyi to si fi i han gẹgẹ bii ẹni ti ko lahun rara.
Ọkunrin agbẹnusọ naa ni lọjọ kan, ni 2017, wọn fi oun joye ni ilu kan ni ipinlẹ Ẹnugu, oun si sọ fun aarẹ naa pe awọn kan ma fi oun joye o, Aarẹ si sọ foun pe oye aa mọri, ṣugbọn iyalẹnu oun ni pe Buhari lo fun oun lowo ti oun fi ko gbogbo ẹbi ati awọn ọrẹ oun lọ sibẹ, pẹlu owo ti oun paapaa na. Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko ni i sọ iye ti Aarẹ fun oun, sibẹ o fẹnu ara rẹ sọ pe owo nla ni.
Adeṣina ni nigba keji, oun fẹẹ lọ si ibi idanilẹkọọ kan ni orilẹ-ede Ṣaina ni, awọn oṣiṣẹ ijọba ni wọn ṣeto naafun. O ni nigba ti Buhari gbọ, o ni ki oun ri oun ti oun ba ti fẹẹ lọ,nigba ti irin-ajo naa si ku ọjọ meji loun yọju si i. N l’Aarẹ ba gbe apo iwe kan foun, nigba ti oun si ṣi i wo, owo dọla lo kun inu rẹ fọfọ. Ọkunrin naa ni oun ko ni i sọ iye rẹ, ṣugbọn owo nla ni. O ni gbogbo eleyii ti oun n wi yii, lati fi han gbogbo aye pe Buhari ko lahun pẹẹ pẹẹ ni!