Buhari loun yoo tọju mọlẹbi awọn to ku soju ija ni Borno

 Faith Adebọla

 Aarẹ ilẹ wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti ṣeleri pe ijọba oun yoo tubọ pese itọju ati atilẹyin to yẹ fawọn mọlẹbi, ara ati ọrẹ to padanu awọn eeyan wọn soju ija tawọn ọmoogun ilẹ wa n koju rẹ lọwọ pẹlu awọn afẹmiṣofo Boko Haram nipinlẹ Borno.

Lasiko abẹwo rẹ sipinlẹ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lo ṣeleri ọhun nibudo awọn ologun ilẹ wa to wa ni Maimalari, niluu Maiduguri, nigba to n ba ikọ awọn jagunjagun ‘Operation HADIN KAI’ ti wọn n koju awọn Boko Haram lọwọ lagbegbe naa sọrọ.

Aarẹ gboṣuba fawọn ọmọ ogun ilẹ wa fun bi wọn ṣe fi tọkan- tara ja lati le awọn afẹmiṣofo naa, o si fun wọn niṣiiri lati ma ṣe kaaarẹ ọkan, o ni wọn o gbọdọ jẹ kawọn Boko Haram ri imu mi, bẹẹ ni wọn o gbọdọ ri oorun sun, niṣe ni ki wọn maa dana ibọn ya wọn titi ti wọn yoo fi rẹyin awọn apamọlẹkun agbesunmọmi ẹda ọhun.

Aarẹ ni: “Inu mi dun lati wa pẹlu yin lọsan-an yii, lati ba yin sọrọ lasiko abẹwo mi sipinlẹ yii. Mo fẹẹ lo anfaani yii lati fi da yin loju pe titi lae lorileede yii maa mọ riri ẹmi ifẹ-ilu-ẹni tẹ ẹ ni ati gbogbo isapa tẹ ẹ ṣe lati ja fun ilẹ baba yin, lati fopin si iwa janduku, ifẹmiṣofo ati iwa ọdaran nilẹ wa.

Mo gboṣuba fun yin, mo si ranti awọn akọni to padanu ẹmi wọn loju ija yii, mo ba awọn mọlẹbi wọn kẹdun gidi, mo si ṣadura fun ẹmi awọn to ti lọ, mo fẹẹ fi da yin loju pe iṣakoso mi ko ni i kẹrẹ lati fun gbogbo awọn mọlẹbi awọn oloogbe wọnyi ni itọju ati atilẹyin to yẹ, ki awọn aya wọn to di opo ati awọn ọmọ wọn to di ọmọ orukan le mọ pe orileede yii mọyi ẹmi ẹni wọn to ku.

Bakan naa ni Aarẹ ṣeleri lati fun awọn ti wọn fara pa loju ija ni itọju iṣegun to dara ju lọ.

Bakan naa ni Buhari tun ṣeleri pe awọn nnkan ija atamatase to jẹ tigbalode tawọn fẹẹ ko wọle latilu oyinbo ti wa loju ọna, o si maa tẹ wọn lọwọ laipẹ. O ni kawọn ọmọ ogun naa ma ṣe rẹwẹsi rara, ki wọn wa lojufo gidi, tori toju-tiyẹ l’Aparo fi n riran.

Buhari ni ti ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ ko le tan leeekanna ni ki wọn fọrọ ija naa ṣe, ki wọn si fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn ọmoogun orileede to wa layiika ẹnubode ilẹ wa, bii Chad ati Cameroun.

Leave a Reply