Buhari ni bawọn gomina ṣe fofin de dida maaluu nigboro, ifiya jẹ Fulani ni

Faith Adebọla

Aarẹ orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti fajuro si bawọn gomina iha Guusu ilẹ wa ṣe lawọn fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba lawọn agbegbe ipinlẹ wọn, o ni ofin naa tẹ ẹtọ ati ominira awọn Fulani darandaran loju.

Atẹjade kan lati ọfiisi Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Mallam Garba Shehu, lọjọ Aje, Mọnde yii, sọ pe bi ipinnu awọn gomina yii ṣe ta ko ofin ilẹ wa, to ṣi n kọ aarẹ lominu, bẹẹ lo fẹsun kan awọn gomina naa pe niṣe ni wọn n dọgbọn ki ọrọ oṣelu bọ ọrọ pataki to jẹ mọ iṣoro aabo, o ni niṣe lawọn gomina naa fẹẹ maa dọgbọn fi bawọn ṣe lagbara to han.

Atẹjade naa ka lapa kan pe: “Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ipinnu oun ni lati mojuto ikọlu-kọgba to n waye lemọlemọ laarin awọn darandaran atawọn agbẹ, lọna ti ojuutu naa yoo fi wa pẹ titi, ti iṣoro awọn darandaran agbebọnrin to n fẹmi eeyan ṣofo yoo fi dohun igbagbe pẹlu.

“Aarẹ ti faṣẹ si awọn igbesẹ kan lati le yanju awọn iṣoro yii patapata nibaamu pẹlu imọran ti Alaaji Sabo Nanono to jẹ minisita feto ọgbin mu wa ninu abọ iwadii kan to fi jiṣẹ fun aarẹ, koda latinu oṣu kẹrin ọdun yii laarẹ ti faṣẹ si awọn aba naa, ṣaaju kawọn gomina iha Guusu ilẹ wa too ṣepade wọn, eyi ti wọn fẹẹ fi dọgbọn fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba, atawọn ipinnu to lọwọ kan oṣelu ninu mi-in ti wọn ṣe lati dọgbọn fihan pe awọn lagbara.

“Ko ruju rara, ohun to foju han ni pe awọn ipinnu wọn ko le mu ojuutu wa si gbogbo gbọnmi-si-i-omi-o-to-o to ti waye lemọlemọ laarin awọn agbẹ atawọn darandaran lati irandiran sẹyin.

“Ṣugbọn awọn eeyan agbegbe Guusu ilẹ wa, ati gbogbo ọmọ orileede Naijiria lati ipinlẹ yoowu ko jẹ, gbọdọ reti pe kawọn adari wọn wa ojuutu si iṣoro ati iya to n jẹ wọn ni, ki i ṣe kawọn aṣaaju maa ṣe bii ẹni n wẹ ọwọ rẹ mọ ninu ọrọ, tabi ki kaluku maa ni oun n ja fẹtọọ ipinlẹ oun.

“Ootọ kan to wa nibẹ ni pe ipinnu awọn gomina naa, o kọọyan lominu, ko si jọ pe o ta ko ofin ilẹ wa, tori ofin ilẹ wa fun gbogbo ọmọ Naijiria lagbara lati ni ẹtọ ati ominira kan naa nipinlẹ eyikeyii kari gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji ta a ni, lai ka ibi yoowu ki wọn ti bi wọn si tabi ẹya yoowu ti wọn le jẹ.

“Ko sẹni ti ọrọ eto aabo to mẹhẹ yii ka lara ju Aarẹ lọ, ṣaaju kawọn gomina too lawọn n ṣe ipinnu ti wọn ṣe ọhun nileeṣẹ aarẹ ti n gbe awọn igbesẹ to yẹ.”

Bẹẹ ni Buhari kede.

Leave a Reply