Buhari ni ko si atunto kankan to maa waye, alaimọkan lawọn to n sọ bẹẹ

Faith Adebọla, Eko

 Aarẹ orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari ti ṣi aṣọ loju eegun erongba rẹ si ọrọ tawọn eeyan n sọ pe dandan ni ki atunto waye si eto iṣejọba lorileede yii ki nnkan too le lọ daadaa, o ni ọrọ ti ko mọyan lori lọrọ ọhun, oun o si fara mọ iru ọrọ alaimọkan bẹẹ.

Buhari sọrọ yii niluu Abuja nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, nigba to n ṣefilọlẹ ajọ Kudirat Abiọla Sabon Gari Peace Foundation. Akọwe agba fun ajọ to n pawo wọle sapo ijọba, (Revenue Mobilization and Allocation and Fiscal Commission), Alaaji Mohammed Bello Shehu, lo gbẹnu Aarẹ sọrọ nibi ayẹyẹ naa.

Aarẹ ni gbogbo ọpọ igba tawọn eeyan ba sọrọ nipa atunto iṣejọba ni mo maa n beere pe ki la fẹẹ tun to, tori ko ye mi.

“Tẹ ẹ ba bi ọpọ ọmọ Naijiria nipa ohun ti wọn ni lọkan lori ariwo atunto to gbode yii, ẹ maa ri i pe wọn o ni i ri nnkan gidi kan sọ.

Awọn kan lara wọn o tiẹ ti i ṣi iwe ofin ilẹ wa ti ọdun 1999 yẹn wo ri, debii pe wọn aa mọ ohun to wa ninu ẹ, bẹẹ ida aadọrin si ọgọrin ohun to wa ninu iwe ofin tọdun 1979 lo wa ninu ti 1999 ti a n lo yii.

Ko buru lati beere fun atunto tabi atunyẹwo iwe ofin ilẹ wa, ṣugbọn ohun to ṣe pataki ju lọwọ yii ni bawọn ijọba ibilẹ ṣe maa duro lori ẹsẹ wọn, ki wọn si riṣẹ gidi ṣe faraalu, ati bi awọn ijọba ipinlẹ ṣe maa jẹ ki ile aṣofin ati ti idajọ duro laaye kaluku wọn.

Ohun ti emi reti kawọn araalu ṣe ni pe ki wọn jẹ kawọn aṣofin apapọ ṣofin to maa jẹ ki ẹka iṣakoso kọọkan duro saaye ẹ, ki ọkan ma jẹ gbaba le omi-in lori. Bi iyẹn ba waye, o maa ṣee ṣe fawọn alaga ijọba ibilẹ atawọn ọba alaye lagbegbe wọn lati fikun lukun, ki wọn si mọ ojutuu si ohunkohun to ba n yọ wọn lẹnu lagbegbe wọn.

Ohun ti mo reti kawọn ti wọn n pariwo atunto ati ipinya ṣe niyẹn. Bẹẹ si ree, ọpọ awọn to n pariwo yii lẹru n ba lati wọnu oṣelu, ti wọn ba tiẹ ṣoṣelu paapaa, wọn o le jawe olubori. Ko si si ijọba eyikeyii lagbaaye to le fa agbara iṣakoso le ẹni tawọn eeyan ko dibo yan lọwọ.

Ẹ n sọ fun wa pe ka pa eto iṣakoso to wa nilẹ ti sẹgbẹẹ kan, ka waa ṣepade apero lati ṣẹṣẹ jiroro bi orileede yoo ṣe tẹsiwaju, iyẹn o le ṣẹlẹ laye, tori ko sorileede to le gba iru ẹ. Niṣe ni ki kaluku pada sọdọ awọn aṣofin to n ṣoju fun wọn lagbegbe wọn, ki wọn si beere atunṣe ti wọn ba n fẹ si ofin ilẹ wa.

Awọn ti wọn n pe fun ipinya ati atunto wọnyi, mo le sọ fun yin pe awọn kan lara wọn, ope ati alaimọkan ni wọn, alarekereke to lewu ni wọn. Awọn ti ko mọ bi ogun ti ri ati atubọtan ogun ni wọn n sọrọ naa, tori orileede Naijiria tobi laarin awọn orileede Iwọ-Oorun Afrika.”

Leave a Reply