‘Ẹ o gbọdọ mu Sunday Igboho, ẹ o si gbọdọ pa a o’, Fani-Kayọde lo ṣekilọ yii lori bi ileeṣẹ Aarẹ ṣe sọ pe ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Muhammed Adamu, ti paṣẹ pe ki kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ fọwọ ofin mu ọkunrin naa, ki wọn si gbe e wa si Abuja.
Ọmọ bibi ilu Ileefẹ, to tun figba kan jẹ minisita fun ileeṣẹ ọkọ ofurufu nilẹ wa, Fani-Kayọde, ṣe ikilọ
yii lori ikanni abẹyẹfo rẹ (twitter), pe yoo jẹ ohun to lewu, ti ko si ni i mu eeso rere kankan jade bi ijọba Buhari ba ni ki wọn mu Sunday ti mọle, tabi ti ohunkohun ba ṣẹlẹ si i.
Fani-Kayọde ni ijọba apapọ gbọdọ ṣọra ṣe lori ọrọ Igboho, nitori o ni atilẹyin gbogbo ọmọ Yoruba lori awọn ohun to n ṣe yii. Ọkunrin yii ni nigba ti awọn ọdọ ilẹ Hausa pariwo nigba kan pe ki awọn Ibo fi Oke-Ọya silẹ, awọn ko fẹẹ ri wọn mọ, ko sẹni to wọn mu si i. O ni ki lo waa de ti wọn yoo mu Sunday, tabi ti wọn yoo pa a nitori pe o sọ fun awọn Fulani darandaran pe ki wọn fi ilẹ Yoruba silẹ.
Ọkunrin naa ni bi wọn ba pa a, wọn sọ ọ di akọni ilẹ Oduduwa, niyẹn, bi wọn ba si mu un, wọn sọ ọ di akikanju ọkunrin ọmọ Yoruba latigba ta a ti gba ominira niyẹn. Ọna yoowu to si wu ki wọn gba, oun naa lo bori.
Fani-Kayọde ni Sunday ko sọ pe ki gbogbo Fulani kuro nilẹ Yoruba patapata, awọn ti wọn n paayan, ti wọn n jiiyan gbe, ti wọn n dunkooko mọ ẹmi awọn eeyan Ibarapa lo ni ki wọn kuro nibẹ.
O waa gboriyin fun Sunday Igboho fun igbesẹ akikanju to gbe yii, eyi to ni awọn ọmọ Yoruba mi-in ko le gbe.