Buhari paṣẹ fawọn gomina: Ẹ pada sile, ẹ lọọ ṣeto pẹlu awọn ọba alaye lori eto aabo

Dada Ajikanje

Bi awọn eeyan kan ṣe n ke si Muhammadu Buhari ko kọwe fipo silẹ lori bi eto aabo ṣe n fojoojumọ mẹhẹ ni Naijiria, Aarẹ paapaa ti sọ fawọn gomina pe ki awọn naa pada lọ si ipinlẹ wọn, ki wọn lọọ fọwọsowọpọ pẹlu awọn oba alaye, ki wahala eto aabo le yanju ni Naijiria.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo sọrọ naa nibi ipade to waye laarin Aarẹ Naijiria atawọn gomina mẹrindinlogoji to wa lorilẹ-ede yii niluu Abuja, nibẹ naa ni Buhari ti ke si awọn gomina, to si rọ wọn pe o ṣe pataki lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọba alaye lori ọrọ eto aabo, ki alaafia le jọba ni Naijiria.

Ninu ọrọ ti oluranlọwọ nipa eto iroyin ati ikede fun Aarẹ, Mallam Garba Shehu, fi sita ni Buhari ti sọ pe ti ajọṣepọ to mọyan lori ba n waye laarin awọn gomina atawọn ọba alaye pẹlu awọn araalu, loju-ẹsẹ ni eto aabo yoo yatọ, ti gbogbo ete awọn oniṣẹ ibi yoo si bajẹ, eyi ti yoo ran awọn agbofinro lọwọ paapaa lati ṣiṣẹ wọn daadaa.

Buhari ni latigba ti ijọba Muammar Gaddafi, ti orilẹ-ede Libya, ti da wo ni wahala awọn janduku ti pọ si i latari bi awọn eeyan kan ṣe ri awọn ohun ija oloro ko wọle loriṣiiriṣii.

O ni ijọba oun ko dakẹ rara lori eto aabo, ati pe oun ko ṣetan lati lọ sori tẹlifiṣan maa kede bi oun ṣe fẹẹ gbogun ti wahala awọn ajinigbe atawọn afẹmiṣofo to n da Naijiria laamu.

 

Leave a Reply