Ijọba apapọ ṣi ẹnubode mẹrin, o ni kawọn yooku ṣi wa ni titi

Faith Adebola, Eko

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fọwọ si i l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, niluu Abuja pe ki wọn ṣi awọn ẹnubode ilẹ wa mẹrin, lati faaye gba ajọṣe okoowo ati ọrọ-aje laarin orileede Naijiria atawọn orileede ti ẹnubode naa kan.

Awọn ẹnubode to paṣẹ pe ki wọn ṣi lẹyẹ-o-sọka ọhun ni ẹnubode Sẹmẹ, lapa Guusu/Iwọ-Oorun, ẹnubode Ilela ati Maitagiri, lagbegbe Ariwa/Iwọ-Oorun Naijiria, ati ẹnubode Mfun, lapa Guusu orileede yii.

 

Buhari ni awọn ẹnubode yooku yoo ṣi wa ni titi, bo tilẹ jẹ pe o ṣee ṣe kawọn naa di ṣiṣi laipẹ, o ni eyi da lori bi eto aabo ati ọrọ-aje ba ṣe n lọ si latari awọn mẹrin ti wọn si yii.

Tẹ o ba gbagbe, latinu oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, lawọn ẹnubode ori ilẹ kaakiri orileede yii ti wa ni pipade, ti ijọba si wọgi le anfaani okoowo ati ka-ra-ka-ta to maa n waye lawọn ẹnubode wọnyi. Ijọba ni iwa fayawọ ounjẹ bii irẹsi ati tọki, pẹlu awọn nnkan ija ogun tawọn eeyan n ko wọlu lati ẹnubode wọnyi lo jẹ ki wọn paṣẹ naa, bo tilẹ jẹ pe eyi ti mu inira pupọ wa fawọn araalu.

Leave a Reply