Aderohunmu Kazeem
Lọjọ Aiku, Sannde, ni Olori oṣisẹ ninu ijọba Aarẹ Muahmmadu Buhari, Alhaji Ibrahim Gambari, ati minisita feto iroyin ati aṣa, Lai Muhammed, atawọn minisita mi-in ṣabẹwo si Bọla Tinubu.
Lati mu ileri ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe pe awọn ọmọ igbimọ oun yoo maa lọ kaakiri ipinlẹ lati ṣabẹwo sawọn ibi ti wọn kọ lu lasiko rogbodiyan SARS, ninu eyi ti ọpọ dukia ti bajẹ, ti ọpọ ẹmi si ṣofo pẹlu ni wọn sọ pe o gbe wọn wa si Eko.
Ṣe lara awọn ti wọn ba dukia wọn jẹ ni Aṣiwaju Bọla Tinubu wa. Ni bayii, Aarẹ Muhammadu Buhari naa ti gbe awọn igbimọ ẹ ti wọn jọ n ṣejọba niluu Abuja dide lati waa ki agba oṣelu inu ẹgbẹ APC yii l’Ekoo.
Awọn minisita ti wọn jẹ ọmọ Yoruba ninu ijọba Buhari ni wọn ba Ibrahim Gambari waa ṣabẹwọ ọhun. Lara wọn ni Babatunde Fashọla; Ọlọrunnimbẹ Mamora; Lai Mohammed, ati Sunday Dare. Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ba wọn de ile Bọla Tinubu n’Ikoyi.
Tẹ o ba gbagbe, ofo nla ni awọn janduku kan fi ṣe awọn dukia Bọla Tinubu lọjọ ti wahala nla ṣẹlẹ ni too-geeti Lẹkki. Ariwo to gba ilu ni pe Bọla Tinubu lo ni kawọn ṣọja lọọ kọ lu awọn to n ṣewọde, eyi gan-an lo bi awọn ọdọ kan ninu ti wọn fi kọ lu ileeṣẹ tẹlifiṣan re, Television Continental, ati iwe iroyin The Nation, to jẹ ti Aṣiwaju oloṣelu naa ni Naijiria.