Buhari ti buwọlu u pe kẹni to ba tapa sofin Korona lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa

Faith Adebọla

 

O ti dofin bayii, pẹlu ibuwọlu Aarẹ Buhari, pe ẹwọn oṣu mẹfa lo n duro de ẹnikẹni to ba tapa sawọn ofin ati alakalẹ ijọba lori didena arankalẹ arun Koronafairọọsi nilẹ wa.

 

Ọjọruu, Wẹsidee yii, ni Aarẹ Muhammadu Buhari buwọ lu abadofin tuntun naa, ti yoo bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ.

Apa mẹfa ọtọọtọ ni wọn pin ofin ti wọn pe akọle ẹ ni ‘Ilana idaabobo ilera kuro lọwọ arun Korona ti ọdun 2021’ (Coronavirus Disease Health Protection Regulations 2021) naa si, ofin merinlelogoji si ni wọn to lẹsẹẹsẹ sinu iwe naa.

Apa ki-in-ni sọrọ nipa awọn alakalẹ to de ikorajọpọ ero ati awọn gbedeke to rọ mọ ọn. Lara ẹ ni pe kawọn eeyan nibikibi ma ṣe kora jọ ninu ile tabi gbọgan ju aadọta lọ, wọn si gbọdọ jinna sira, o kere tan, mita meji gbọdọ wa laarin wọn siraawọn.

Apa keji da lori awọn alakalẹ to kan ṣiṣi awọn ọja, awọn ọja igbalode (supermarkets and malls), ṣọọbu itaja, awọn ile igbafẹ, gareeji onimọto, ile idaraya, otẹẹli ati gbọngan ariya. Ofin mọkanlelogun lo wa ni apa yii. Lara ẹ ni pe ki ẹnikẹni ti ko ba lo ibomu tabi ti ko wọ ọ daadaa, ti ko si ni kẹmika apakokoro lọwọ, ma ṣe wọ ọkọ ero, tabi wọ ileetaja ti ero pọ si, tabi ileejọsin, titi kan banki atawọn ileeṣẹ.

Apa kẹta sọrọ nipa awọn igbesẹ to pọn dandan feeyan to ba fura pe oun ti lugbadi Korona, ofin naa si ka a leewọ fẹnikẹni lati sa kuro ni ibudo iyasọtọ tabi ileewosan ti wọn ti n tọju Koro.

Ọrọ nipa ijiya ati igbẹjọ ẹnikẹni to ba tapa sawọn ofin ti wọn to lẹsẹẹsẹ si apa ki-in-ni de ikẹrin lo wa ni apa kẹrin. Ni taara ni ofin naa sọ pe kẹnikẹni ti wọn ba mu lọọ fara han niwaju adajọ, ẹwọn oṣu mẹfa, o kere tan, ni ofin naa sọ pe wọn maa sọ ẹni to ba ṣẹ si i si, tabi ko san owo itanran, tabi mejeeji.

Lapa karun-un, ofin naa gbe agbara wọ awọn agbofinro bii ọlọpaa, Sifu Difẹnsi, ṣọja, awọn ẹṣọ alaabo ati imọtoto lati fọwọ ṣinkun ofin mu awọn eeyan to ba tasẹ agẹrẹ sawọn ofin wọnyi, ki wọn si gbe irufẹ ẹni bẹẹ dele-ẹjọ lai sọsẹ.

Leave a Reply