Aderounmu Kazeem
Aarẹ orile-ede yii, Muhammed Buhari, ti ki Gomina Godwin Obaseki ku oriire, bi ajọ eleto idibo, INEC ṣe kede wi pe oun lo jawe olubori.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun Aarẹ, Ọgbẹni Garba Shehu, fi sita lo ti sọ pe, Muhammed Buhari ti ni, “Ipinnu mi fun eto idibo to yaranti ko mi rara, nitori ti a ko ba ṣeto idibo to fẹsẹ mulẹ, akoba nla ni yoo jẹ fun opo to mu eto iṣejoba orilẹ-ede yii duro.’’
Aarẹ Buhari fi kun un pe, “Ohun to ṣe pataki si mi ni ṣiṣe eto idibo to yaranti, nitori iyẹn gan–an lo le fun wa ni eto iṣejoba dẹmokiresi to dara.”
Bakan naa lo sọ pe, ti ibo tawọn eeyan ba n di ko ba ṣiṣẹ ninu iyanisipo awọn aṣoju wọn, irufẹ nnkan bayii yoo sọ eto ijọba dẹmokiresi di otunbantẹ ni.’’
Buhari ti waa ki awọn eeyan Edo ku oriire, bẹẹ lo dupẹ lọwọ ajọ INEC, atawọn agbofinro lori abajade ibo ọhun to lọ wọọrọwọ.