Buhari ti paṣẹ: Ẹnikẹni tẹ ẹ ba ti ri pẹlu ibọn AK-47, ẹ yinbọn pa a

Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun awọn ẹṣọ alaabo ilẹ wa lati wọ awọn inu igbo lọ, ẹnikẹni ti wọn ba si ti ri to gbe ibọn alagbara ti wọn n pe ni AK-47 lọwọ to n kiri inu igbo, ki wọn yinbọn pa a.

Ninu ifọrọwerọ kan ti Akọwe rẹ lori eto iroyin, Garba Sheu ṣe pẹlu BBC Hausa niluu Abuja, lo ti gbẹnu Aarẹ sọrọ yii.

Garba ni Aarẹ ti paṣẹ fun awọn agbofinro yii lati yi inu igbo kaakiri, ẹnikẹni ti wọn ba ti ri to gbe ibọn AK-47 tabi awọn ibọn to lagbara lọwọ kiri, ki wọn yinbọn pa a loju ẹsẹ.

 

Leave a Reply