Buhari ti pada de lati London

Adewumi Adegoke

Ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ni Aarẹ Muhammadu Buhari pada si ilẹ Naijiria lẹyin irinajo ọlọsẹ meji to ti ni oun fẹẹ lọọ ri awọn dokita oun ni London.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ to de yii din ọjọ meji si iye ọjọ to yẹ ko pada si Naijiria, Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Femi Adeṣina, ni pipada ti Aarẹ tete pada de yii fi han pe ko sohun to ṣe baba naa, kanpe ni ilera rẹ wa.

Ati pe wiwa to pada wa yii yoo mu ojutuu ba gbogbo fa-a-ka-ja- to ti n lọ ninu ẹgbẹ APC nigba ti ko si nile. Yoo si le ba wọn mojuto gbogbo ohun to yẹ bi ipade gbogbogboo wọn yoo ṣe waye ni Satide ọsẹ to n bọ.

Awọn lọgaa lọgaa lẹnu iṣẹ ijọba, ninu eyi ti Olori awọn oṣiṣẹ ọọfiisi rẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, dari ni wọn waa pade rẹ ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe to wa niluu Abuja, ni nnkan bii aago meje kọja iṣẹju

mẹwaa.

Leave a Reply