Faith Adebọla
Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Muhammadu ko si nile, to jẹ ilu oyinbo lo wa to ti lọọ ri awọn dokita rẹ, sibẹ, ọkunrin naa ti paṣẹ pe igbimọ alamoojuto ti Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni, ni ko ṣeto ipade gbogbogboo ẹgbẹ naa ti yoo waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Aarẹ Buhari lo kọwe si Gomina ipinlẹ Kebbi to jẹ alaga awọn gomina ẹgbẹ APC, Abubakar Atiku Bagudu, l’Ọjọruu, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, lori igbesẹ tuntun yii.
Ninu iwe naa lo ti fi aidunnu rẹ han si gbogbo wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa, leyii to mu ki ọpọlọpọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ gba ile-ẹjọ lọ, eyi to ni o le mu ki ajọ eleto idibo fagi le gbogbo eto idibo tawọn ba ṣe laarin ara awọn.
Bakan naa lo ni ko ṣee ṣe fun ẹgbẹ naa lati ṣamulo awọn igbimọ apaṣẹ tuntun fun ẹgbẹ naa nitori asiko perete ti awọn ni, ati gbogbo ofin to rọ mọ ọn.
Buhari ni, ‘‘O ṣe pataki fun ẹgbẹ naa lati yago fun gbogbo ariyanjiyan ati gbigbe ara ẹni lọ si ile-ẹjọ ati gbogbo awọn nnkan mi-in to le di wa lọwọ, ka si tete ko ara wa papọ kiakia.
‘‘Latari idi eyi, mo paṣẹ bayii pe: Ki ipo adari awọn alamoojuto pada si bo ti wa tẹlẹ.
‘‘Lọna keji, ki gbogbo ẹgbẹ awọn gomina atawọn alatilẹyin wọn yago fun ọrọ tabi iwa to le mu iyapa wa ninu ẹgbẹ naa, to si tun le ṣakoba fun ipade gbogbogboo ẹgbẹ yii.
‘‘Lọna kẹta, igbimọ alamoojuto ti Mai Mala Buni n dari rẹ ni ki wọn fun laaye lati tẹsiwaju ninu gbogbo ipalẹmọ to ba yẹ fun eto ipade gbogbogboo ẹgbẹ naa ti yoo waye lọsẹ to n bọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni gbogbo rẹ bẹrẹ si i rọ gbudugbudu ninu ẹgbẹ APC, ti wọn si sọ pe wọn ti yọ alaga igbimọ to n mojuto ẹgbẹ naa tun jẹ Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Bala Bunni nipo naa, wọn si fi Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sani Bello, si i.
Ọkunrin yii ni wọn ni yoo ṣeto idibo gbogbogboo ẹgbẹ naa ti yoo waye lọsẹ to n bọ, bẹẹ ni wọn ti fi iwe bi wọn ti pin awọn oye ẹgbẹ naa kaakiri awọn ẹkun kaakiri ilẹ wa ṣọwọ si i.
Ṣugbọn oju-ẹsẹ ni ajọ eleto idibo ti ni awọn ko le gba ohunkohun ti ẹgbẹ naa ba ṣe wọle nitori alaga igbimọ alaboojuto ti wọn ṣẹṣẹ yan yii ko si labẹ ofin.
Bẹẹ ni ọpọ ọmọ ẹgbẹ yii ti n gbera wọn lọ sile-ẹjọ lori ẹsun kan tabi omi-in, ko too di pe Aarẹ Buhari ṣẹṣẹ waa da si yii.
Pẹlu igbeṣẹ Aarẹ yii, o ṣee ṣe ki gbogbo fa-a-ka-ja-a to ti n lọ laarin ẹgbẹ naa rodo lọọ mumi.