Buhari ti yan Buba Marwa sipo alaga ajọ NDLEA

Aarẹ Muhammadu Buhari ti yan gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ laye ijọba ologun, Alhaji Buba Marwa, sipo ọga agba fún àjọ to n ri sí àwọn tó n gbe egboogi oloro, NDLEA.

Ọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé yii, ni wọn kede iyansipo tuntun yii.

Ṣaaju àsìkò yìí ni Buba Marwa ti di ipo alaga fún igbimọ ti Ààrẹ gbe kalẹ lori aṣilo ogun mu.

Wọn ni ipa manigbagbe to ko ninu igbimọ ọhun lo ṣokunfa ipo alaga ajọ NDLEA ti Ààrẹ Muhammed Buhari yan an sí bayii.

Pẹlu igbesẹ yii, ohun ti awọn awọn eeyan n sọ ni pe ọkunrin naa yóò ṣaṣeyọri latari ipa dáadáa tó ko lasiko to ṣe gomina ipinlẹ Eko.

Ṣa o, awọn mi-in náà ko ṣai sọ pé lara ojúṣàájú ti wọn mọ ijọba Buhari si naa lo tun ṣe bayii pẹlu bo ṣe yan ọkunrin ọmọ ipinlẹ Adamawa naa sipo ọga àgbà fún àjọ NDLEA. Niwọn igba to jẹ pe awọn eeyan to wa lati adugbo naa lo n di ipo pataki pataki mu latẹyinwa ninu ijọba rẹ.

Leave a Reply