Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Aarẹ Muhammadu Buhari ti yan igbakeji ọga ọlọpaa tẹlẹ, Alkali Usman Baba, gẹgẹ bii adele ọga ọlọpaa pata ni Naijiria bayii.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Buhari fọwọ si iyansipo ọga ọlọpaa ọmọ ipinlẹ Yobe naa. Minisita fọrọ awọn ọlọpaa, Maigari Dingyadi, lo sọ iyansipo naa di mimọ fawọn akọroyin l’Abuja.
Usman Alkali Baba lo gbapo lọwọ Mohammed Adamu, ẹni ti Buhari sun asiko to yẹ ko fẹyinti siwaju.
Ọdun 1963 ni wọn bi Usman Baba nipinlẹ Yobe. Yunifasiti Bayero, ni Kano, ati ti ilu Maiduguri lo ti kawe. Ọdun 1998 lo darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa ilẹ wa.