Buhari yan ọga ileeṣẹ sifu difẹnsi ati ọgba-ẹwọn, Hausa lawọn mejeeji

Faith Adebọla

Ọgbẹni Ahmed Abubakar Audi nijọba fọwọ si bayii lati di ọga agba tuntun fun ileeṣẹ Sifu Difẹnsi (Nigeria Security and Civil Defence Corps) ilẹ wa.

Aarẹ Muhammadu Buhari lo buwọ lu iyansipo ọkunrin naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, niluu Abuja. Ẹni tuntun yii maa gbaṣẹ lọwọ Ọgbẹni Abdullahi Gana Muhammadu, to ti wa nipo naa tẹlẹ.

Ninu atẹjade kan lati ọfiisi Alukoro ẹka ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹlẹ nilẹ wa, Ọgbẹni Mohammed Manga, o sọ pe niṣe ni Buhari fẹsọ ṣayẹwo awọn ti wọn dabaa fun ipo naa lati mọ bi wọn ṣe tẹwọn, ti wọn si kunju oṣuwọn si, ko too buwọ lu Audi lati dipo naa mu.

Bakan naa, atẹjade ọhun tun fidi rẹ mulẹ pe Aarẹ Buhari ti yan Ọgbẹni Haliru Nababa lati bọ si ipo ọga agba ileeṣẹ to n bojuto ọgba ẹwọn lorileede yii, Nigeria Correctional Service.

Minisita fun ileeṣẹ ọrọ abẹle ti ranṣẹ ikini ku oriire sawọn mejeeji ti wọn ṣẹṣẹ yan wọnyi, o si gba wọn niyanju lati ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹka agbofinro to ku, ki wọn si lo aaye tuntun yii lati mu ilọsiwaju ba awọn ileeṣẹ ti wọn fi wọn ṣolori ẹ.

Leave a Reply