Buhari yari, o ni, ‘E ma ba mi le awọn eeyan mi lọ!’

Aarẹ orilẹ-ede yiii, Ọgagun agba Muhammadu Buhari ti yari mọ awọn aṣofin Naijiria lọwọ bayii o, o ni oun ko ni i gba ki wọn le awọn eeyan lara oun, oun ko si ni i gba ki wọn ba oun le awọn ti oun gbeṣẹ fun lọ. Ohun to faja yii ni aṣẹ ti awọn aṣofin pa lanaa pe ki gbogbo awọn olori ologun ilẹ wa fi ipo wọn silẹ, nitori apa wọn ko ka ọrọ eto aabo orilẹ-ede yii mọ: ki wọn maa lọ, ki Buhari si fawọn mi-in rọpo wọn.

Ṣe ni tootọ, o pẹ ti pupọ ninu awọn to lẹnu niluu, ati awọn ara ilẹ okeere paapaa, ti n sọ pe ki Buhari paarọ awọn olori ogun yii, pe ati olori awọn ṣọja ni o, ati ti awọn ọmọ ogun ofuurufu, ati ti awọn ọmọ ogun oju omi, gbogbo wọn lo jọ pe o ti rẹ, wọn ko si ni ọgbọn tabi ilana tuntun kan ti won le fi koju ogun Boko Haram mọ, nitori lati ọjọ ti wọn ti wa lẹnu e, kaka ki ewe agbọn dẹ ni o, koko lo n le. Ọrọ naa ni ile igbimọ aṣofin agba tẹ le lanaa, ni wọn ba jawee ‘ẹ-sun-sẹgbẹẹ-kan’ fun wọn.

Ṣugbọn ọrọ naa ko tẹ Aarẹ Buhari lọrun rara, nitori ẹsẹkẹsẹ ti iroyin ohun ti awọn aṣofin ṣe yii ti jade ni ileeṣẹ-aarẹ ti gbe iwe jade pe Buhari ko fẹ ohun ti awọn aṣofin naa ṣe rara, ko si ni i gba. Ninu iwe naa ti Fẹmi Adeṣina ti i ṣe alukoro fun Aarẹ fọwọ si, Buhari ni awọn aṣofin yii kọ ni wọn ba oun yan awọn olori ogun oun, oun loun yan wọn, gẹgẹ bii ọkan lara awọn ojuṣe oun, bi oun ko ba si fẹ wọn mọ naa, oun loun le le wọn lọ. O ni ki wọn ma baun le awọn ọrẹ oun lọ o jare!

 

Leave a Reply