Buhari yii ko mọ nnkan kan mọ, ko sigba ti wọn ko ni i ji gbe lọ – Buba Galadima

Faith Adebọla

Eekan oloṣelu apa Oke-Ọya ilẹ wa to ti figba kan jẹ alatilẹyin timọtimọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Alaaji Buba Galadima, ti sọ pe ibi ti eto aabo bajẹ de yii ti taṣiiri Buhari pe ko lọgbọn kan to le da si i mọ, tori ọkunrin naa ko mọ nnkan kan mọ, ati pe ti Aarẹ ko ba ṣọra daadaa, ko sigba ti wọn o ni i ji oun naa gbe lọ.

Ọkunrin yii, to jẹ eekan ẹgbẹ All Progressives Congress tẹlẹ, ko too lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu New Nigerian Peoples Party (NNPP) sọrọ ikilọ ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keje yii, nigba to n kopa ninu ifọrọwanilẹnuwo kan tileeṣẹ BBC ṣe fun un.

Nigba ti wọn bi i leere oju to fi wo eto aabo labẹ ijọba Buhari, o ni: “Awọn agbebọn yii ko naani ijọba Buhari mọ. Nibẹrẹ, wọn kọkọ ṣe bii ẹni bẹru ẹ, wọn lero pe o maa jẹwọ akin loju ogun fawọn, ṣugbọn ni bayii wọn ti ri aṣiri ẹ pe aja to n gbo lasan ti ko le geeyan jẹ ni.

Buhari ko mọ nnkan kan, ko le ṣe ohunkohun, idi si niyẹn tẹ ẹ fi n ri awọn onṣejọba pẹlu rẹ ti wọn n ji ẹgbẹlẹmuku owo ko ni koto ọba, ti ko si sẹni to le da wọn lọwọ kọ.

Tawọn agbebọn ba le ṣakọlu si ọgba ẹwọn Kuje, l’Abuja, to jẹ olu-ilu Naijiria, ki wọn si lọ bẹẹ, o fihan pe ko si aabo fun Aarẹ niyẹn o. Ta o ba si ṣọra, o pẹ ni, o ya ni, wọn le ji Buhari funra ẹ gbe, pẹlu bi wọn ṣe n fọrọ eto aabo pa mi-in-din yii.”

O ni gbogbo agbara tijọba yii le sa ni wọn ti sa yii, afi kijọba naa tun bọ sọwọ ẹlomi-in la too le mọ bi wọn yoo ṣe yanju ipenija aabo.

Tẹ o ba gbagbe, ninu fidio kan tawọn agbebọn afẹmiṣofo fi lede lopin ọsẹ to lọ yii, wọn ṣafihan awọn ero ọkọ reluwee ti wọn ji ko lọna Abuja si Ibadan, lẹyin ti wọn ti ṣakọlu si oju-irin reluwee naa ni wọn ti n fi ọpa lu awọn to ṣẹku sakata wọn ninu awọn ero naa, wọn fiya jẹ wọn, wọn si sọ pe tawọn o ba ri owo tawọn beere lati tu wọn silẹ, niṣe lawọn maa pa wọn danu tabi ki wọn ta wọn soko ẹru.

Ninu fidio ọhun, to ṣi n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara bayii, ni wọn ti ṣeleri pe laipẹ awọn maa ji Aarẹ Buhari tabi kawọn pa a, ati gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai gbe, lọjọ kan.

Leave a Reply