Ọlawale Ajao, Ibadan
Nigba ti ọmọdekunrin ọlọpọlọ pipe kan, Opuofoni Freeborn Ebimotimi, wa nileewe fasiti, to n ta awọn ẹgbẹ ẹ yọ, ireti gbogbo eeyan ni pe ologo eeyan kan lọmọkunrin ọmọ Ijaw naa yoo ya lọjọ iwaju. Ṣugbọn kaka ki ireti daradara naa wa si imuṣẹ, igbesi aye ipọnju lo n gbe, nitori ti ko niṣẹ lọwọ, awọn obi rẹ ti ku, nigba ti ebi fẹẹ pa ọmọkunrin yii ku ni wọn lo gbetiju ta, lo ba lọọ ji burẹdi gbe, ibẹ lo si ti pade iku ojiji, nitori niṣe lawọn ọdọ t’ara n kan lu u titi to fi ku, ni gbogbo iwe ati ijafafa ọmọkunrin naa ba ja sofo.
Laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, niṣẹlẹ to ba ni ninu jẹ ọhun waye laduugbo kan ti wọn n pe ni Honeyhill, lagbegbe Tombia, nipinlẹ Bayelsa.
Ọmọkunrin ta a gbọ pe wọn bi si adugbo Korkorosei, ni ẹkun Ijaw, lo kẹkọọ-gboye onipo kin-in-ni ninu imọ iṣakoso ọrọ aje (Bussiness Administration) nileewe giga Fasiti Ibadan.
Bi wọn ṣe ka a mọ ibi to ti ji burẹdi gbe ni wọn ti bẹrẹ si i lu u lati kọ ọ lọgbọn pe ole jija ko yẹ ọmọ eniyan.
Bo tilẹ jẹ pe aaanu ọmọkunrin yii ṣe awọn kan, ti wọn sare si i, ti wọn si sọ fun awọn to n lu u pe ki wọn fi i silẹ, awọn yoo sanwo burẹdi naa, ki wọn ma lu u pa, niṣe lawọn eeyan naa faake kọri, wọn si lu u titi ti ẹmi fi bọ lara ẹ.
Aburo oloogbe naa, Idisemi Opuofoni Freeborn ṣalaye pe latigba ti baba awọn ti ku ni aye ko ti rọrun fawọn lati gbe, o ni ebi lo sun ẹgbọn oun debi to fi lọọ ji burẹdi naa gbe.
Ọmọbinrin naa ni ọmọ meje ni awọn obi awọn bi, ati pe latigba ti baba awọn ti ku ni nnkan ko ti ri bakan naa fun awọn mọ. O ni ọdun ọdun 2019 loun ti ṣedanwo iwe mẹwaa, ṣugbọn ti oun ko le lọ si yunifasiti nitori pe ko sowo lati lọ.
Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ naa, tawọn kan si n sọ pe ohun ti awọn ijọba sọ awọn ọdọ ilẹ wa da niyi. Wọn ni ọmọ to kawe to fi wa ni ipele akọkọ ti wọn n pe ni (First Class) nileewe giga fasiti, to ba jẹ pe o riṣẹ ṣe ni, ko sohun to maa sun un de idi ole jija. Ati pe o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pe nitori burẹdi lasan ni wọn ṣe gbẹmi ọmọ to ni ọjọ ọla to daa bẹẹ.