Oluyinka Soyemi Lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ilẹ wa iba yege fun idije ilẹ Afrika ọdun 2022 ti yoo waye nilẹ Cameroon, ṣugbọn ami-ayo odo si odo ti wọn gba pẹlu Sierra Leone ti ba nnkan jẹ. Bo tilẹ jẹ pe awa la wa …
Read More »Champions League: Eyi lawọn kilọọbu ti yoo figagbaga
Idije UEFA Champions League yoo bẹrẹ logunjọ, oṣu yii, awọn alaṣẹ si ti ṣeto ipin mẹjọ fawọn kilọọbu ti yoo kopa nibẹ. Awọn ipin ọhun niyi: Ipin A: Bayern Munich, Atletico Madrid, Red Bull Salzburg, Lokomotiv Moscow Ipin B: Real Madrid, Shakhtar Donetsk, Inter Milan, Borussia Monchengladbach Ipin C: Porto, Man City, …
Read More »Israel Adesanya, ọmọ Naijiria to n ja ijakadi fagba han wọn ni Abu Dhabi
Ọmọ ilẹ wa to n ja lagbo ijakadi Ultimate fighting Championship (UFC), Israel Adesanya, ti fitan tuntun balẹ bayii pẹlu bo ṣe di ami-ẹyẹ Middleweight Champion mu lẹyin to na Paulo Cpsta ilẹ Brazil. Ija naa to waye niluu Abu Dhabi, nilẹ United Arab Emirate, ni Costa fẹẹ lo lati …
Read More »Efe Ajagba gba ife-ẹyẹ kẹrinla lagbo ẹṣẹ kikan
Oluyinka Soyemi Ọmọ ilẹ wa to n ṣe bẹbẹ lagbo ẹṣẹ kikan lagbaaye, Efe Ajagba, ti gba ami-ẹyẹ kẹrinla bayii lẹyin to na Jonnie Rice ilẹ Amẹrika lalẹ ana ni gbọngan The Bubble, to wa ni Vegas, nilẹ Amẹrika. Lẹyin ipele kẹwaa ija naa lawọn adajọ mẹtẹẹta, iyẹn Max DeLuca, Adalaide Byrd …
Read More »Umar Sadiq dero ileewosan lẹyin ija ni Russia
Oluyinka Soyemi Abẹṣẹ-ku-bii-ojo ọmọ ilẹ wa, Umar Sadiq, ti n gba itọju nileeowsan bayii lẹyin ija to ja pẹlu Fyodor Chudinov nilẹ Russia. Ẹni ọdun mejilelọgbọn naa ni wọn sọ pe o pọ ẹjẹ lẹyin to fidi-rẹmi nipele to gbẹyin ija WBA Gold Belt, eyi lo si jẹ ki wọn …
Read More »Ife-ẹyẹ idije Afrika poora ni Egypt
Oluyinka Soyemi Ife-ẹyẹ ilẹ Afrika to wa lọwọ Egypt ti poora kuro ni olu-ile ajọ ere bọọlu ilẹ Afrika to wa ni Cairo, nilẹ Egypt. Ṣe ni iroyin naa deede gba ilu kan lonii pe wọn ji ife-eyẹ naa, ṣugbọn Magdi Abdelghani to jẹ ọmọ igbimọ ajọ CAF sọ pe ọdun 2013 …
Read More »Ẹ fi papa iṣere Ilọrin sọri Rashidi Yẹkini- Pinnick
Stephen Ajagbe, Ilọrin Lọna ati bu ọla fun ogbontarigi agbabọọlu ilẹ wa to ti doloogbe, Rashidi Yẹkini, ati lati maa ṣeranti rẹ, Aarẹ ajọ to n ṣakoso ere bọọlu lorilẹ-ede Naijiria, Amaju Pinnick, ti rọ Gomina Abdulrahman Abdulrazaq lati fi orukọ agbabọọlu naa sọ papa iṣere to wa niluu Ilọrin yii. Pinnick …
Read More »Ideye darapọ mọ Goztepe ilẹ Turkey
Oluyinka Soyemi Agbabọọlu ilẹ Naijiria, Brown Ideye, ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Goztepe ilẹ Turkey. Gẹgẹ bi awọn alaṣẹ kilọọbu naa ṣe sọ, iwe adehun ọlọdun meji ni agbabọọlu ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ọhun tọwọ bọ. Turkey ni orilẹ-ede kẹsan-an ti Ideye yoo ti gba bọọlu, ilẹ Naijiria lo si ti …
Read More »Bayern lu Barca laluwo pẹlu ami-ayo mẹjọ si meji
Iya ami-ayo mẹjọ si meji ki i ṣe nnkan ti ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ilẹ Spain ro pe awọn yoo jẹ lọwọ Bayern Munich ilẹ Germany nibi idije Champions League tọdun yii to n lọ lọwọ, ṣugbọn wọn jẹ iya naa lajẹbanu lalẹ oni. Agbabọọlu mẹfa lo fi goolu mẹjọ pa …
Read More »Willian balẹ si Arsenal lẹyin ọdun meje ni Chelsea
Oluyinka Soyemi Agbabọọlu Chelsea tẹlẹ, Willian Borges da Silva, ti balẹ si Arsenal lẹyin to tọwọ bọ iwe adehun ọlọdun mẹta pẹlu kilọọbu tuntun ọhun. Ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa gbe igbesẹ yii lẹyin ọdun meje ni Chelsea, nigba ti idunaa-dura ko si wọ mọ lo kẹru ẹ. Ọmọ ilẹ Brazil …
Read More »Awọn eeyan ba agbabọọlu ilẹ wa, Ahmed Musa, yọ fun ọmọkunrin lantilanti lo bi
Oluyinka Soyemi Ikinni ‘ẹ-ku-oriire’ lawọn eeyan n ki atamatasẹ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles to n ṣe bẹbẹ ni Al-Nassr, ilẹ Saudi Arabia, Ahmed Musa, bayii pẹlu ọmọ tuntun jojolo tiyawo rẹ ṣẹṣẹ bi. Musa funra ẹ lo kede ọrọ naa pe Juliet Ejue, iyawo keji toun fẹ, ti bimọ ọkunrin …
Read More »