Faith Adebọla Gbogbo akitiyan Amofin agba Peter Ọlọrunniṣola lati gba beeli fun onibaara rẹ, Ọgbẹni Dibu Ọjẹrinde, to ti figba kan jẹ ọga agba fun ajọ JAMB ilẹ wa, lo fori ṣanpọn ni kootu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, niṣe nile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn da baba naa pada sọgba …
Read More »Ijọba ti ko awọn ọlọpaa SWAT ti wọn fi rọpo SARS jade
Faith Adebọla, Eko Ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, IGP Mohammed Adamu, ti paṣẹ lojọ Aje, Mọnde, pe ki wọn da awọn ikọ ọlọpaa afọgbọn-jagun (Special Weapon and Tactical Team) SWAT, ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ jade kaakiri origun mẹrẹẹrin Naijiria sita lẹyẹ-o-sọka. Ninu atẹjade kan ti Adamu kọ si gbogbo …
Read More »Azikiwe bori awọn ọta ẹ, o loun yoo di aarẹ alagbada ni 1979 ṣaa ni
Ọlayiwọla Alaga Ni ọjọ kejilelogun, oṣu karun-unm 1979, ẹsẹ ko gbero ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ Anambra igba naa, gẹgẹ bi Adajọ Araka ti ṣe sọ. Ọjọ naa ni wọn fẹẹ mọ ibi ti ẹjọ ti Oloye Nnamdi Azikiwe to fẹẹ du ipo aarẹ Naijiria lorukọ ẹgbẹ oloṣelu NPP yoo fori …
Read More »Wọn la maneja banki mẹwọn l’Ekoo, ọgọsan-an miliọnu naira lo poora mọ ọn lọwọ
Faith Adebọla, Eko Ọgba ẹwọn to wa l’Alagbọn, Ikoyi, nipinlẹ Eko, nile-ẹjọ giga tijọba apapọ kan paṣẹ pe ki wọn sọ maneja banki Zenith kan si, wọn lọkunrin naa ko le ṣalaye bi ọgọsan-an miliọnu naira ṣe dawati mọ ọn lọwọ ni banki ọhun, bẹẹ wọn lowo naa ki i …
Read More »Ija Nnamdi Azikiwe pẹlu ajọ FEDECO to nṣeto ibo lọdun 1979 (2)
Ohun ti ọrọ owo-ori awọn ti wọn fẹẹ du ipo aarẹ lasiko idibo ọdun 1979 yẹn da silẹ, nnkan rẹpẹtẹ ma ni o. Diẹ lo ku ki ọrọ naa da ọpọlọpọ eto ti wọn ti ṣe silẹ fun idibo ọhun ru pata. Nnamdi Azikiwe, baba to fẹẹ du ipo naa …
Read More »Ija Nnamdi Azikiwe pẹlu ajọ FEDECO to n ṣeto ibo lọdun 1979
Ko si tabi ṣugbọn kan nibẹ pe ọgbọn oloṣelu ni Oloye Nnamdi Azikiwe fẹẹ lo fun awọn ti wọn n ṣeto idibo, o si fẹẹ fi juujuu bo gbogbo eeyan loju ni. Ofin eto idibo ti la ọrọ naa kalẹ, ohun ti ofin naa si sọ ni pe ki gbogbo eeyan …
Read More »Azikiwe binu lasiko ibo 1979, o loun yoo gba ile-ẹjọ lọ
Ninu ofin eto idibo ọdun 1979, kinni kan wa nibẹ ti wọn fi ha a. Wọn ṣalaye ninu ofin naa pe ẹnikẹni ti ko ba sanwo ori ẹ ko lẹtọọ lati du ipo aarẹ, tabi ti gomina. Iyẹn ni pe ẹni yoowu ti yoo ba du ipo aarẹ, tabi ti …
Read More »Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (14)
*Idi abajọ ree o Gbogbo ohun to ṣẹlẹ pata laye ijọba Yakubu Gowon ati ti Muritala nipa ileeṣẹ ITT ati Moshood Abiọla to ni in ni Naijria, gbogbo ẹ lo wa lọwọ Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ to n du ipo Aarẹ Naijiria lorukọ ẹgbẹ oṣelu UPN ni 1979. Bi ọrọ naa si …
Read More »Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (13)
*Idi abajọ ree o (13) Lọjọ ti Theophilus Akindele yoo pada si ẹnu iṣẹ ẹ, nnkan mi-in ṣẹlẹ si ọfiisi wọn. Loootọ ni ile iṣẹ ITT tawọn Abiọla ti gba iṣẹ ti wọn fẹẹ gba lọwọ ijọba apapọ nipa agbara Ọgagun Muritala Muhammed gẹgẹ bii kọmiṣanna (minisita) eto ibanisọrọ, ṣugbọn …
Read More »Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (12)
*Idi abajọ ree o Inu Ọgagun Muritala Muhammed ko dun rara si ohun ti Ọgagun agba Yakubu Gowon, olori ijọba Naijiria nigba naa, ṣe fun Theophilus Akindele yii. Muritala fẹ ki wọn le ọkunrin naa kuro lẹnu iṣẹ ijọba pata ni, ko fẹ idaduro fungba diẹ ti Gowon ṣe fun un. …
Read More »Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (11)
*Idi abajọ ree o Ọjọ nla kan ni ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 1974, jẹ ninu itan ijọba Naijiria, fun awọn ti wọn ba mọ itan naa daadaa. Ọjọ Aje, Mọnde, lọjọ naa, ọjọ ti igbimọ apaṣẹ ijọba ologun Naijiria igba naa n ṣe ipade wọn ni. Ohun kan ṣoṣo …
Read More »