Charles Soludo ẹgbẹ APGA di gomina Anambra

Faith Adebọla

 Ajọ eleto idibo apapọ ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC), ti kede pe Ọjọgbọn Charles Chukwuma Soludo, ti ẹgbẹ oṣelu Alakukọ, All Progressives Grand Alliance (APGA), lo jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina ipinlẹ Anambra to waye lọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun yii, oun ni yoo si di gomina ipinlẹ naa loṣu keji, ọdun to n bọ.

Alakooso ajọ ọhun fun eto idibo yii, Ọjọgbọn Florence Obi, to kede abajade esi idibo ọhun laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, niluu Awka, ipinlẹ Anambra, sọ pe: “Mo kede pe, Soludo, to ni ibo to pọ ju lọ, ti ibo rẹ si ju ida meji ninu mẹta apapọ ibo ti wọn di ni ijọba ibilẹ mọkanlelogun to wa nipinlẹ Anambra, lo yege eto idibo sipo gomina yii, oun lo jawe olubori.”

Soludo, ẹni ọdun mọkanlelọgọta (61), yege ni ijọba ibilẹ mọkandinlogun, ninu mọkanlelogun ti wọn ti dibo, aropọ ibo rẹ si jẹ ẹgbẹrun lọna mejilelaaadọfa, okoolerugba ati mẹsan-an (112,229).

Ẹgbẹ oṣelu PDP (Peoples Democratic Party) lo ṣe ipo keji, aropọ ibo ẹgbẹrun mẹtalelaaadọta, ẹgbẹrin le meje (53,807) ni wọn di fun Ọgbẹni Valetine Ozigbo to dije labẹ asia ẹgbẹ naa, wọn si yege ni ijọba ibilẹ kan.

Ipo kẹta ni Sẹnetọ Andy Uba ti ẹgbẹ oṣelu APC (All Progressives Congress) wa pẹlu aropọ ibo ẹgbẹrun mẹtalelogoji, ọrinlerugba ati marun-un (43,805), ṣugbọn wọn ko yege ni ijọba ibilẹ kankan.

Ẹgbẹ oṣelu YPP to fa Sẹnetọ Ifeanyi Uba kalẹ lo tun yege nijọba ibilẹ kan to ku, ṣugbọn ibo perete ni wọn ni.

Gẹrẹ ti wọn ti dibo tan lọjọ Satide ni Ọjọgbọn Soludo ti n lewaju ninu awọn esi idibo ijọba ibilẹ ogun (20) to wọle, ṣugbọn wọn ko kede rẹ bii olubori nibaamu pẹlu ofin eto idibo INEC nitori idibo ti ko le waye nijọba ibilẹ Ihiala. Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni ibo too waye nijọba ibilẹ Ihiala kan ṣoṣo to ku.

Ọjọgbọn Soludo, ọmọ bibi ilu Isuanioma, nijọba ibilẹ Aguata, ipinlẹ Anambra, ni wọn bi lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 1960, o kawe gboye ninu imọ ọrọ-aje (Economics) lọdun 1984 ni Fasiti Naijiria to wa niluu Nsukka, nipinlẹ Enugu, wọn si yan an sipo gomina banki apapọ ilẹ wa (Central Bank of Nigeria), loṣu karun-un, ọdun 1984, lasiko iṣejọba Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ.

Ọkunrin naa jade dupo gomina Anambra lẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2009, ṣugbọn Peter Obi lo wọle lẹgbẹ APGA, lati ọdun 2013 lo si ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APGA, bo tilẹ jẹ pe wọn ko fa a kalẹ lawọn eto idibo to waye sipo gomina ṣaaju asiko yii.

Leave a Reply