Chidinma ti wọn lo pa baba alaaanu rẹ loun o jẹbi, ile-ẹjọ ti da a pada sẹwọn

Faith Adebọla, Eko

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn da afurasi ọdaran akẹkọọ Fasiti Eko, ẹni ọdun mejilelogun nni, Chidinma Ojukwu, ti wọn fẹsun kan pe oun lo ṣekupa Ọga agba ileeṣẹ tẹlifiṣan Super TV, Ọgbẹni Usifo Ataga, lọjọsi, pada satimọle, latari bo ṣe sẹ kanlẹ pe oun o jẹbi ẹsun naa.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni wọn wọ Chidinma lọ sile-ẹjọ giga ọhun to wa lagbegbe Tafawa Balewa Square, l’Erekuṣu Eko, nipinlẹ Eko, ẹsun mẹjọ ni wọn ka si i lẹsẹ, lara rẹ da lori iṣikapaniyan, lilu jibiti, ole jija ati igbimọpọ lati huwa ibi.

Yatọ si Chidinma, awọn meji mi-in ti wọn jọ kawọ pọyin rojọ niwaju Adajọ Yetunde Adesanya ni kootu ọhun ni aburo Chidinma, Chioma Egbuchu, ti wọn fẹsun kan pe wọn ba ẹru ole lọwọ ẹ, wọn loun ni wọn ka iPhone 7 to jẹ ti oloogbe naa mọ lọwọ, ati Ọgbẹni Quadri Adedapọ, ti wọn loun naa lọwọ ninu ṣiṣekupa Ataga.

Chioma ni tiẹ loun o jẹbi ẹsun rira ọja ole, o loun kọ loun n lo iPhone 7 ti wọn n sọrọ rẹ yii, o loun le ṣalaye bọrọ ṣe jẹ gan-an tile-ẹjọ ba gba oun laaye.

Abilekọ Ọlayinka Adeyẹmi lati ẹka to n gbọ ẹjọ araalu nipinlẹ Eko lo n ba awọn afurasi ọdaran naa ṣẹjọ, o ṣalaye pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni wọn mu Chidinma lori ẹsun ipaniyan, ati pe afurasi ọdaran naa ti fẹnu ara ẹ jẹwọ ni gbangba pe oun mọ nipa iku ojiji to mu oloogbe naa lọ, o loun fi ọbẹ gun un leralera  ninu yara otẹẹli tawọn jọ sun si lagbegbe Lẹkki, nibi tiṣẹlẹ naa ti waye ni.

Ṣugbọn Chidinma tun yi ọrọ pada ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe fawọn oniroyin ninu oṣu keje, ọdun yii, o ni oun o si ninu yara naa nigba ti wọn pa oloogbe yii, o loun ti jade lọọ ran nnkan, oloogbe naa si tilẹkun pa boun ṣe jade, ṣugbọn nigba toun pada de, oun kanlẹkun, ko sẹni to dahun, loun ba ṣakiyesi pe wọn o fi kọkọrọ tilẹkun naa pa, wiwọle toun si wọle, inu agbara ẹjẹ loun ba Ọgbẹni Ataga, o ti ku.

O loun tun ṣakiyesi pe gbogbo inu ile naa ti daru, o ti yatọ si boun ṣe fi i si nigba toun n jade lọ, to fihan pe ijakadi waye laarin oloogbe naa atawọn to ṣakọlu si i.

O ni idi toun fi ‘purọ mọ ara oun lakọọkọ’ ni pe oun ro pe ko ni i sẹni to maa gba oun gbọ toun ba sọ pe oun o mọ nipa iku rẹ, tori awọn meji pere naa lawọn jọ wa ninu yara ọhun fun ọjọ meji kiṣẹlẹ yii too waye.

Bakan naa ni ọkan lara awọn mọlẹbi oloogbe naa sọ fawọn oniroyin lasiko ti wọn n sinku Ataga pe apa to wa lọrun ọwọ oloogbe naa fihan pe niṣe ni wọn de e lokun pinpin ki wọn too pa a, bi ile naa si ṣe daru ati ipo ti oku rẹ wa lasiko tawọn agbofinro de’bẹ fihan pe ki i ṣe Chidinma nikan lo da iṣẹ naa ṣe, o ni lati jẹ pe awọn eeyan mi-in pẹlu lati gbẹmi oloogbe ọhun.

Ṣa, Adajọ Yetunde Adesanya ti ni ki wọn da gbogbo wọn pada sọgba ẹwọn Kirikiri, titi ti igbẹjọ to kan yoo fi waye loṣu kọkanla, ọdun yii.

Leave a Reply

%d bloggers like this: