Dandan ni abẹrẹ ajẹsara Korona fun gbogbo oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo-Akeredolu

Jọkẹ Amọri

 Ijọba ipinlẹ Ondo ki kede pe k’eku ile yaa gbọ, ko lọọ sọ fun t’oko, ọran-an-yan ni gbigba abẹrẹ ajẹsara Korona nipinlẹ Ondo, paapaa fawọn oṣiṣẹ ijọba atawọn olukọ, tori ko ni i saaye fẹnikẹni ti ko ba gbabẹrẹ naa lati wọle sọfiisi rẹ bẹrẹ lati ọjọ ki-in-ni, oṣu kọkanla to wọle de yii.

Ọrọ yii wa ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ ọhun, Ọgbẹni Donald Ọjọgọ, fi lede lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii pe ijọba ṣe ipinnu yii lẹyin ipade pataki kan ti wọn ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ẹka ileeṣẹ ijọba gbogbo laipẹ yii.

O ni ipade naa ti fẹnu ko lori gbedeke ọjọ ti wọn maa faaye gba awọn oṣiṣẹ ti wọn o ti i gbabẹrẹ Korona lati maa ba iṣẹ wọn lọ.

Kọmiṣanna naa ṣalaye pe irọ ni awuyewuye ati ahesọ tawọn eeyan n gbe kiri pe abẹrẹ naa lewu, o ni ko siṣoro kan nipa abẹrẹ ajẹsara Korona, o si pọn dandan lati gba a, ki isapa ijọba lati dena arankalẹ arun yii le fẹsẹ mulẹ.

Atẹjade naa fi kun un pe awọn oṣiṣẹ gbọdọ mu ẹri ti wọn ni dani pe wọn ti gbabẹrẹ Korona, ẹri naa si gbọdọ jẹ ojulowo.

O ni ijọba ko ni i yọnda kawọn ti ko gba abẹrẹ ajẹsara ṣakoba fun ilera awọn to ti gba abẹrẹ naa, niṣe lawọn maa ti iru awọn ẹni bẹẹ mọ ẹyin ode ọfiisi wọn.

Leave a Reply