Dandan ni ki APC bori ibo 2023, a o fẹẹ pẹjọ rara – Adamu

Faith Adebọla

Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Sẹnetọ Abdullahi Adamu, ti sọ pe dandan lowo ori, ọran-anyan si laṣọ ibora. O ni gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un lati jawe olubori sipo aarẹ lọdun 2023, o ni ko si yiyan mi-in fawọn ju iyẹn lọ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an yii, lọkunrin naa sọrọ yii lasiko ti iyawo oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu naa to tun jẹ sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan Aarin-Gbungbun Eko lọwọlọwọ, Abilekọ Olurẹmi Tinubu, ṣabẹwo si i l’Abuja, ti wọn si jọ fikun lukun. Iyawo igbakeji oludije funpo aarẹ, Abilekọ Nana Shettima naa wa nibi ijiroro naa.

Lẹyin ti Adamu ti tẹti si ọrọ ti Tinubu ati Nana ba wa, eyi to da lori bi wọn ṣe maa ko awọn obinrin jọ kaakiri orileede yii lati gbaruku ti awọn ọkọ wọn mejeeji, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Kashim Shettima, ti wọn n dije funpo aarẹ ati igbakeji aarẹ, Abdullahi fesi pe:

“Mo fẹẹ lo anfaani abẹwo yin yii lati tẹnu mọ ọn pe a gbọdọ ṣiṣẹ ki ẹgbẹ oṣelu wa le yege ni. A o ni yiyan mi-in, ko si ti wa loju lati sọ bẹẹ.

“A ko ṣiṣẹ lati kọri sile-ẹjọ lẹyin idibo, a n ṣiṣẹ lati wọle sile agbara ni Aso Rock ni. Tori bẹẹ, mo fẹẹ fi da yin loju pe gbogbo wa jọ maa ṣiṣẹ yii ni. Ohunkohun to ba yẹ ka ṣe, ohunkohun tẹ ẹ ba fẹ, a maa ṣe e lati ti yin lẹyin.

“K’Ọlọrun tubọ ba wa daabo bo awọn oludije wa, ko si fun wọn lọgbọn. A mọ pe ohun tawọn araalu n reti ga, awa naa si mọ nnkan ta a gbọdọ ṣe.  Igba ẹkẹ ni i dawọ tile, agbajọ ọwọ si la fi i sọya, a jọ maa ṣiṣẹ yii ni.

“A mọ pe ọgọọrọ awọn ọlọpọlọ pipe lo wa laarin ẹyin obinrin, o kan jẹ pe ẹ o raaye to ni. A mọ pe awọn alaapọn pọ ninu yin.  Tori bi nnkan ṣe ri, a o ti i fun ẹyin obinrin lanfaani to, kẹ ẹ le ṣafihan gbogbo agbara yin.

“Ṣugbọn ni ti eto idibo to n bọ yii, APC gbọdọ wọle ni, a maa ṣiṣẹ fun un gidi.”

Leave a Reply