Dandan ni ki Fayẹmi dupo aarẹ ni 2023 – APC Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) tipinlẹ Ekiti ti ni dandan ni ki Gomina Kayọde Fayẹmi dupo aarẹ ilẹ Naijiria lọdun 2023, bi ko tilẹ wu u ko ṣe e.

Alaga igbimọ fidi-hẹ ẹgbẹ naa, Ọnarebu Paul Ọmọtọṣọ, lo sọrọ yii niluu Ayede-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ, lasiko ti oloye ẹgbẹ naa kan, Ọmọwe Oluṣẹgun Ọṣinkọlu, ṣayẹyẹ Keresi fun ẹgbẹrun kan ọmọ ẹgbẹ ọhun lẹkun idibo Ariwa Ekiti.

Ọmọtọṣọ, ẹni ti Ọnarebu Ade Ajayi to jẹ Alukoro ẹgbẹ naa ṣoju fun, sọ pe bo tilẹ jẹ pe Fayẹmi ko ti i fifẹ han si ipo aarẹ, awọn yoo ri i daju o pe dupo naa dandan nitori iṣẹ nla to ti ṣe lagbo oṣelu.

Ọmọtọṣọ ni, ‘‘Gbogbo ẹnu la le fi sọrọ pe APC ni yoo tun jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ yii lọdun 2022, nitori awọn nnkan ribiribi ti Fayẹmi ti ṣe, a ko si fẹ ki ẹgbẹ rau-rau kan gbajọba ki wọn tun ba Ekiti jẹ.

‘‘Lori ipo aarẹ ni 2023, asiko ti to ki aarẹ wa lati Ekiti. Idi niyi ta a fi n rọ gbogbo yin kẹ ẹ ṣatilẹyin fun Gomina Fayẹmi.

‘‘Bo tilẹ jẹ pe Fayẹmi ko ti i sọ pe oun fẹẹ dupo, a maa wọ ọ sinu idije naa dandan ni nitori o kunju oṣuwọn, o ni ifarajin, bẹẹ lo jẹ oloootọ si APC.

Bakan naa ni Ọmọtọṣọ gboriyin fun Ọsinkọlu to jẹ alaga ipolongo fun Buhari ati Oṣinbajo nipinlẹ Ekiti lasiko ibo ọdun 2019, ẹni to ni o duro ṣinṣin sinu ẹgbẹ, bo tilẹ jẹ pe igba meji lo padanu anfaani lati di sẹnetọ.

Ninu ọrọ Ọṣinkọlu ti amugbalẹgbẹẹ ẹ, Ọgbẹni Ayọdeji Ọlọrunfẹmi, ṣoju fun, o bẹ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati sowọ pọ, ki wọn si ṣatilẹyin ti ko lẹgbẹ fun APC, eyi to pe ni ẹgbẹ gbogbo araalu.

Leave a Reply