Daniel fẹẹ para ẹ n’Iyana-Ipaja, awọn LASEMA ni wọn doola ẹmi ẹ

Faith Adebọla, Eko.

Ọpẹlọpẹ awọn ẹṣọ alaabo ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ti wọn tete debẹ, awọn ni wọn o jẹ ki baale ile kan, Daniel Chibuike Bassi, gbẹmi ara ẹ lagbegbe Iyana-Ipaja, niṣe lọkunrin naa gun opo ẹrọ tẹlifoonu adugbo naa, o fẹẹ bẹ latori opo giga fiofio naa.

Nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lọkunrin naa gun opo ọhun, wọn ni niṣe lo fo ọgba onirin ti wọn ṣe opo tẹlifoonu naa, awọn eeyan ko si tete fura pe o fẹẹ ṣera e leṣe ni.

Wọn lawọn kan ti wọn ri ọkunrin naa nigba to kọkọ de saduugbo ọhun sọ pe niṣe lawọn ro pe ọkan lara awọn pasitọ ti wọn maa n waasu kiri opopona ni, awọn ni wọn sare lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni teṣan Gowon Estate, ni wọn ba kan si ajọ NEMA ati ti Lagos State Emergency Management Agency.

Oju-ẹsẹ lawọn oṣiṣẹ ajọ naa ti de ibi iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si doola ẹmi afurasi ọdaran yii.

A gbọ pe awọn agbofinro ti n fọrọ wa ọkunrin naa lẹnu wo lati wadii ohun to ṣẹlẹ to fi fẹẹ gbẹmi ara ẹ lojiji.

Ọga ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Guusu/Iwọ-Oorun, Ibrahim Farinloye, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni iwadii tawọn kọkọ ṣe fihan pe ọkunrin naa gun opo yii lati para ẹ ni.

O ni ọkunrin naa sọ pe iṣẹ Aluminium loun n ṣe lọja Aluminium Village, ati pe agbegbe Dọpẹmu, nijọba ibilẹ Alimọṣọ, loun n gbe, ṣugbọn ko le ranti ọjọ-ori rẹ daadaa, o si loun o mọ ẹmi to ta le oun toun fi bẹrẹ si i pọn opo naa lọ soke, ṣugbọn aye ti su oun.

Ọgbẹni Farinloye ni awọn agbofinro yoo ṣewadii to yẹ lori ẹ, ki wọn too pinnu igbesẹ to tọ labẹ ofin.

Leave a Reply