Daniel fi ọmọ bibi inu ẹ ṣe baranda, eeyan mẹta ọtọọtọ lo ta a fun l’Ogun

Faith Adebọla

Boya aṣa buruku kan ti Portable gbajugbaju onkọrin hipọọpu zahzuu zeeh da ninu awo orin rẹ pe ‘da ju, ka la, huwa ika’, lo sun baale ile ẹni ọgbọn ọdun, ti wọn porukọ ẹ ni Daniel Chigozie yii, huwa ọdaju ati ika to hu yii ni o, oun nikan naa lo le fẹnu ara rẹ ṣalaye, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe niṣe lọkunrin yii wo ṣunṣun, to ta ọmọ bibi ẹ, Daniel Chinonye Darlington, ọmọ oṣu mẹsan-an tiyawo ẹ n tọ lọwọ, eeyan mẹta ọtọọtọ lo si ta ọmọ kan ṣoṣo ọhun fun, to gbowo gọbọi lọwọ ọkọọkan wọn, kaṣiiri ẹ too tu.

Alaye ti Ọga agba ẹṣọ alaabo Amọtẹkun nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni David Akinrẹmi, ṣe ninu atẹjade to fi ṣọwọ s’Alaroye lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta yii, ni pe ni iwadii ranpẹ tawọn ṣe ti fihan pe afurasi ọdaran to n gbe adugbo Abẹla, niluu Sango-Ọta, nipinlẹ Ogun, yii n ṣiṣẹ pẹlu ikọ gbọmọgbọmọ kan ti wọn n feeyan ṣowo ẹru.

O ni awọn to n ṣiṣẹ buruku yii ki i paayan o, wọn o si j’ọmọ gbe gbowo bii tawọn ajinigbe, amọ niṣe lawọn maa n ta ọmọ tọwọ wọn ba ti ba fun awọn onibaara wọn loriṣiiriṣii, wọn aa gbowo, lẹyin eyi, awọn ti wọn ta ọmọ naa ni wọn tun maa ṣeto bọmọ ọhun yoo ṣe dawati nibikibi ti wọn ba ta a si, kẹni to ra ọmọ ọhun, tabi to n fi ọmọ naa ṣọmọ-ọdọ si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọmọ yoo ti balẹ sibomi-in, iyẹn ibi tuntun tawọn afurasi yii ba tun ta a si, ohun kan naa lo n maa ṣẹlẹ nibẹ pẹlu, kọjọ too gori ọjọ, ọmọ naa yoo dawati nibẹ ni, wọn aa ti gbọna ẹburu mu un kuro, lẹyin tawọn ti gba owo ti wọn ti fowo ṣara rindin.

Wọn ni ọkan lara ikọ yii ni Daniẹl wa, eyi lo mu ko wo raaraara, niṣe lo ki ọmọ ara ẹ mọlẹ, lo ba ta a fawọn mi-in bi wọn ṣe maa n ṣe.

Ẹni to kọkọ ra ọmọ ọhun, wọn o sọ orukọ ẹ, amọ onitọhun ti sanwo, ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira, wan fifiti taosan (N150,000), lo san, amọ ko pẹ tiyẹn o fi ri ọmọ naa mọ, laimọ pe baba ọmọ ti tun ta Chinoye fẹlomi-in, to si ti gbowo ẹ sapo, ẹgbẹrun lọna irinwo, fọọ ọndirẹdi taosan (N400,000) lo gba lọwọ ẹni keji yii, ti wọn loun n gbe lagbegbe Mẹiran, nipinlẹ Eko.

Bakan naa lo tun gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira, sẹbin ọndirẹdi Naira (N700,000) lọwọ onibaara kan toun wa l’Apapa, Dokita Nosa ni wọn porukọ tọhun, ibi ti wọn ti n dọgbọn lati tun mu ọmọ naa kuro nibẹ lawo ti ya, takara si tu sepo.

Nigba tọwọ awọn Amọtẹkun ba afurasi yii, ti wọn si n bi i leere ọrọ, o jẹwọ pe loootọ loun huwa ma-jẹ-a-gbọ ọhun, o ni ki wọn fori ji oun, aajo owo lo sun oun debẹ.

Ṣa, wọn ti mẹjọ Daniẹl lọ sọdọ ajọ ijọba apapọ to n gbogun ti awọn afọmọ-ṣẹru, iyẹn National Agency for the Prohibition of Trafficking in Humans, wọn si ti mu afurasi naa sakata wọn. Wọn ni iwadii ṣi n lọ lọwọ, bẹẹ lawọn agbofinro ti n wa gbogbo awọn tọrọ yii kan, awọn ti wọn n ta ọmọ atawọn ti wọn n ra a. Lẹyin iwadii lo ni awọn afurasi naa yoo kawọ pọnyin rojọ ni kootu.

Leave a Reply