Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Mẹrin lawọn ikọ adigunjale to gba mọto ayọkẹlẹ Camry ti nọmba ẹ jẹ AAA 212 GJ, lọwọ obinrin kan n’Ikoyi, niluu Eko. Ṣugbọn Ogere, nipinlẹ Ogun, ni wọn gbe mọto naa wa, ibẹ lọwọ ti ba Daniel Sunday, ti awọn ọlọpaa si n wa awọn mẹta yooku rẹ bayii.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ni ọwọ ba Daniel, lẹyin ti olobo ta teṣan ọlọpaa Ogere pe awọn ọkunrin mẹrin kan wa lagbegbe Agunwarogo, irisi wọn ati irin ẹsẹ wọn si mu ifura dani pẹlu mọto Camry ti wọn n gbe kiri ni.
Eyi lo mu DPO Ogere, CSP Abiọdun Ayinde, ko awọn ọmọ ẹyin rẹ lọ si agbegbe naa, bi wọn si ti debẹ ti awọn afurasi naa ri wọn ni wọn bẹ lugbẹ, wọn sa lọ patapata.
Daniel yii nikan lọwọ ba, oun naa ko si ki i ṣe ẹran rirọ, o ṣe ọlọpaa kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Peter Ọlajide leṣe gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe fidi ẹ mulẹ.
Nigba tawọn ọlọpaa wonu mọto naa wo ni wọn ri iwe aṣẹ iwakọ ẹni to ni in, nọmba foonu ẹni naa si wa nibẹ, ni wọn ba pe e.
Obinrin kan, Philomena, lo gbe ipe naa, o si fidi ẹ mulẹ pe toun ni mọto ọhun, ati pe Ikoyi, l’Ekoo, lawọn ole naa ti yọbọn soun, ti wọn si gbe e lọ.
Ọbẹ aṣooro ẹlẹnu meji lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ adigunjale yii, wọn si ti gbe e lọ sẹka itọpinpin gẹgẹ bi aṣẹ ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun. Bẹẹ ni wọn yoo wa awọn mẹta to sa lọ ri laipẹ gẹgẹ bo ṣe paṣẹ.