Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ko sẹni to mọ pe Dansu Asogba, ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun yii lọwọ ninu iku ẹgbọn iya ẹ, Iyabọ Dansu, ẹni ọgọta ọdun ti wọn ṣadeede gbọ iku ẹ lọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ, to kọja yii. Afi nigba ti wọn fẹẹ ro oku naa, ti ọmọkunrin yii bẹrẹ si i bẹ awọn agba ile wọn pe ki wọn ma ṣe bẹẹ, nitori oun loun pa iya naa, oun fi irin lu u pa ni.
Ipokia niṣẹlẹ yii ti waye. Ohun ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi, alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣalaye f’ALAROYE ni pe meji ninu awọn ọmọ iya to ku yii lo lọọ ṣalaye fawọn ọlọpaa pe Asogba jẹwọ pe oun loun pa iya naa sinu ile, toun si yọ jade lai jẹ ki ẹnikẹni mọ ohun to ṣẹlẹ.
Alukoro sọ pe awọn ọmọ naa ṣalaye pe ojiji lawọn gbọ iku iya awọn lai jẹ pe o ṣaarẹ tẹlẹ, wọn kan pe awọn lati Ipokia lọjọ naa pe iya awọn ku ni. Wọn ni nigba tawọn ko fura sẹnikẹni lori iku naa lawọn ṣe sin mama naa lai tiẹ sọ fọlọpaa rara, to jẹ awọn gba f’Ọlọrun ni.
Wọn ni ṣugbọn awọn eeyan sọ fawọn pe Asogba ni wọn ri lọdọ iya naa lọjọ to ku ọhun, wọn ni bo ṣe lọ tan ni ko sẹni to gburoo iya nita mọ, afi bo ṣe jẹ oku rẹ ni wọn ba ninu ile.
Iku iya yii fu awọn eeyan agbegbe naa lara pupọ, wọn si lawọn yoo ro oku iya ọhun lati mọ ohun to pa a. Bẹẹ, bi wọn ba ro oku naa, ẹni to ba lọwọ ninu iku rẹ yoo tẹle e lọ sọrun kia ni. Ohun to ba Asogba lẹru ree, lo ba ni ki wọn ma ro oku naa, oun loun pa a.
Nigba ti wọn beere ohun ti ẹgbọn iya rẹ ṣe fun un to fi pa a, Dansu sọ pe oun fura si oloogbe naa pe oun lo pa ọmọ toun kọkọ bi, o ni iyawo oun tun loyun ẹlẹẹkeji, oyun naa tun walẹ, oun si gbagbọ pe ẹgbọn iya oun yii lo wa nidii ẹ, ohun to jẹ koun wọle lọọ pa a niyẹn.
O fi kun un pe irin to ki daadaa kan loun la mọ iya naa lọrun, bo ṣe ku niyẹn.
CP Edward Ajogun, ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, sọ pe iwa ojududu ni keeyan maa nigbagbọ pe ẹnikan lo pa ọmọ oun tabi lo ṣe oun laida, beeyan ba waa fi idajọ sọwọ ara ẹ to pa onitọhun, o ti lufin ijọba, ẹjọ ipaniyan ni yoo si jẹ.
Iyẹn lo fi jẹ ẹka to n ri si ipaniyan ni wọn taari Dansu si fun itẹsiwaju ẹjọ yii, bẹẹ ni CP Ajogun kilọ fawọn eeyan pe ki wọn yee nigbagbọ ninu pe ẹnikan lo n ṣe awọn tabi pe ajẹ lẹnikan.
O ni ẹni to ba paayan nitori o ro pẹ ajẹ ni, lasiko yii ti ọlaju ti de, ti ofin si wa, ẹni naa yoo ba ara ẹ lakolo ijọba.