Gbenga Amos
“Ko sẹni to rufin eto ikọle nipinlẹ Ogun ti ko ni i jẹgba ofin. Ẹnikẹni tabi awọn tajere iwa irufin bii eyi ba ṣi mọ lori yoo fimu kata ofin dandan ni.”
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, lo sọrọ yii ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, fi lede lọjọ Satide, ọjọ kejila, oṣu kẹta yii, lori igbimọ oluṣewadii ti gomina naa yan lati tọpinpin ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ijamba ile alaja kan to wo l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, lọna Ogere, ilu Ipẹru, nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ, nipinlẹ naa.
Eeyan meji la gbọ pe wọn dagbere faye ninu ajalu ọhun, ọgọọrọ awọn to n ṣiṣẹ ikọle lọwọ lasiko tile naa rọ lulẹ lo fara pa yannayanna, wọn si ti ko wọn lọ ọsibitu.
Ninu igbimọ oluṣewadii ẹlẹni mẹrin ti gomina naa yan, wọn fi Kọmiṣanna fun eto ile kikọ, Ọgbẹni Tunji Ọdunlami, ṣe alaga, awọn mi-in ti wọn yoo jọ ṣiṣẹ ọhun ni Oludamọran pataki lori eto ayika, Ọla Adesanya, akẹgbẹ rẹ lẹka ọrọ ilẹ ati aworan ilẹ, Ọlọlade Salami, ati Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle. Wọn ni ki wọn ṣewadii gbogbo ohun to mu ki ijamba naa ṣẹlẹ.
Bakan naa ni atẹjade ọhun fidi ẹ mulẹ pe Gomina Abiọdun ti paṣẹ ki wọn dawọ iṣẹ ikọle duro lẹsẹkẹsẹ nibi iṣẹlẹ naa.
Abiọdun kẹdun pẹlu awọn ti wọn padanu eeyan wọn, o si ṣeleri pe ẹlẹṣẹ kan ki yoo lọ lai jiya, nidii ọrọ yii.