Dapọ Abiọdun buwọ lu aba iṣuna ọdun 2021

 Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti buwọ lu aba iṣuna ọdun 2021. Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yii ni eyi ti waye l’Ọjọruu,Wẹsidee,  ọgbọnjọ oṣu kejila ọdun 2020.

 Aba iṣuna ti wọn pe akọle ẹ ni ‘Budget of Recovery and Sustainability’ naa le lọọọdunrun biliọnu naira(338.6b),ṣugbọn ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, fi sita, o ni awọn atunṣe diẹ ba aba iṣuna  yii lawọn abala kan.

Awọn ẹka ti atunṣe naa kan to mẹrinlelaaadọrin(74) gẹgẹ bi Ṣomọrin  ṣe wi, o si tun ṣalaye pe igbimọ to n ri si owo nina nile igbimọ aṣofin Ogun, eyi ti Ọnarebu Kunle Ṣobukanla n dari lo ṣagbeyẹwo to yẹ ti wọn si ṣe atunṣe lawọn ibi to yẹ ko ti waye ki wọn too da a pada fun gomina.

Ni bayii, biliọnu mọkanlelọgọta 61b)ni wọn yoo na lori eto ile gbigbe, igbayegbadun bii ileegbe, ilera, imojuto ayika ati bẹẹ bẹẹ lọ yoo gba biliọnu mẹtalelaaadọrun(93b). Eto ẹkọ , biliọnu mejidinlọgọta(58b), riro awọn ọdọ lagbara ni wọn yoo na biliọnu mẹfa fun, ọgbin yoo gba biliọnu mẹẹẹdogun(15b).

Nigba to n fi awọn eeyan ipinlẹ Ogun lọkan balẹ pe aba iṣuna yii yoo sapa lati bori iṣoro ti Korona ko ba ọrọ-aje ipinlẹ yii, Gomina Abiọdun sọ pe gbogbo ẹka pata ni agbeyẹwo yoo kan, yoo si jẹ ko ṣee ṣe lati bẹrẹ iṣẹ pẹrẹwu loṣu kin-in-ni ọdun 2021.

Ko ṣai dupẹ lọwọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin naa, labẹ Ọnarebu Taiwo Oluọmọ, fun bi wọn ṣe tete da aba naa pada lai fi falẹ rara.

Leave a Reply